Segun Okewole
Gomina ana nipinle Oyo, Otunba Alao Akala ti tu die lara awon asiri to wa nidii bi ijoba ipinle naa lowolowo labe Gomina Abiola Ajimobi se wo ofiisi gbajumo onkorin igbagbo nni, Yinka Ayefele, nibi ti ileese redio Fresh FM wa.
Otunba Alao Akala so pe aini asoyepo to peye laarin awon olusakoso ileese Fresh FM ati ijoba ipinle Oyo lo fa wiwo ti won wo ileese naa lojiji.
Alao Akala lo tu asiri naa lasiko to n dahun orisirisi ibeere lati enu awon oniroyin lasiko fi erongba e lati pada dije dupo gomina han ni olu ile egbe naa to wa niluu Abujalojo Tusde ana.
O ni awon alakoso ileese naa ni won ko tete gbe igbese to ye ki won gbe lasiko, ti won foju wo o pe kinni ijoba fe e se fawon, idi ni yii tijoba naa fi gbe igbese to gbe naa.
Akala je ko di mi mo pe oun funra oun, pelu boun se je gbajumo oloselu to, oun ni ileese redio toun, Parrot FM loruko e, to si je pe iru leta ti won ko ranse si ileese redio Yinka Ayefele naa ni won ko ranse soun, to si je pe lesekese loun ti so fawon to n sakoso e pe ki won tete loo yanju oro naa.
Ninu oro e, Akala so pe "Mo ro pepe bi won se wo ileese redio Ayefele ko seyin gaapu to wa laarin awon alakoso ileese naa ati ijoba ipinle Oyo.
"E je ki n so fun un yin, won ti yanju oro naa. Mo si fe e ki e mo danu pe mi o paro, tooto ni ma a so fun un yin. Emi naa ni ileese redio, Parrot FM loruko e, Ibadan nipinle Oyo naa lo wa. Iru leta bayii ni won ko ranse sibe, ti won si muu wa fi han mi.
"Nigba ti mo rii, mo so fun won pe, e loo ba won lati yanju oro naa. Won si loo yanju e. Aisi ibasepo to dan monran laarin won lo fa a, won si ti yanju e."
No comments:
Post a Comment