Ojo Satide to koja yi, iyen ojo kejilelogun osu kesan an odun 2018 ni ojo ti oga agba ajo Fijilante tijoba apapo, iyen Vigilante Group of Nigeria, Olanrewaju Nureni Adedoyin ko le tete gbagbe ninu igbesi aye e.
Ko si nnkan meji to fa a bi ko se ti awoodu ti ajo aladani, NGO kan ti won Institute of Corporate Administration gbe fun okunrin to saba maa n gbe iwa alaafia laruge laarin ilu.
Awoodu naa ti won fun gege bi omo egbe naa, iyen Fellow, Institute of Corporate Administration (FCAI) la gbo pe eto ayeye e waye ninu gbongan Center for Management Development to wa niluu Shangisa nipinle Eko.
Nigba to n soro nipa idi ti won fi fun Ogbeni Nureni Adedoyin ni awoodu yi, adari ajo naa, G. C. Onyekwere so pe kii se pe awon deede maa n fun awon eeyan ni awoodu naa, bi ko se awon to ba to sii ni won maa n lanfaani lati gba a.
Onyekwere wa gboriyin fun Adedoyin fun ise takuntakun to n se nipa eto aabo nipinle Ogun to ti je adari egbe Fijilante tijoba apapo.
Bee lo gba a lamonran pe ko tubo tepa mo ise naa, ati pe oun nigbagbo pe Aare Muhammadu Buhari ko nii pe e bu owo lu egbe naa.
Nigba toun naa n soro, Adedoyin Nureni Olanrewaju dupe lowo awon alakoso ajo naa fun bi won se pon on le, ati awoodu naa, o loun yoo tubo sa gbogbo ipa oun lati rii pe eto aabo nipinle Ogun figagbaga pelu ti oke okun.
No comments:
Post a Comment