Aare Ona Kakanfo ile Yoruba, Otunba Gani Adams ti padanu baba to bii lomo.
Gege bi iroyin to te AWIKONKO lowo lai pe yi se so, osibitu aladani kan to wa niluu Eko ni baba naa, Pa Lamidi Adams ku si laaro onii, Satide, latari aisan ojo ogbo ti won lo n daamu e.
Eni ogorin odun (80) ni won pe Pa Lamidi Adams ti won loun lo ni ileese to n fi moto rin irin ajo to wa lagbegbe Oturkpo nipinle Benue ko too darapo mo ileesw Desmony Nigeria Ltd, to si je pe oun ni adari eka igbokegbodo oko nibe.
Bo tile je pe a ko tii gbo nipa ekunrere iroyin naa, sugbon ohun ta a gbo ni pe eto isinku baba naa ko ni pe e waye.
Ekunrere iroyin naa n bo lai pe.
No comments:
Post a Comment