Ileeṣẹ to n ri si
ipolongo Atiku Abubakar fun ti ipo aarẹ labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP ti sọ pe ko si ootọ ninu ahesọ ọrọ kan tawọn kan n gbe
e jade
pe ọkunrin
naa ti n mura lati fẹgbẹ oṣelu naa silẹ lọọ
darapọ
mọ ẹgbẹ mi-in, wọn ni irọ to jinna sootọ ni.
Ninu atẹjade kan ti
Ọgbẹni Ṣẹgun
Ṣowumi,
to jẹ
agbẹnusọ olupolongo fun
ileeṣẹ
naa gbe jade lọjọ Aiku Sannde,
ana an, lo ti sọ
pe awọn
to n gbe igbekugbe naa jade ko niṣẹ ati pe nnkan ti
wọn
ko ri i ni wọn n sọ lati yi ọkan awọn alatilẹyin ọkunrin naa pada
ni wọn
n ṣe e,
eyi to sọ
pe wọn
ti i mu ofo ọjọ keji ọja.
O ni fawọn alaigbagbọ, ko sigba
kankan ti Atiku pinnu lati fẹgbẹ naa silẹ bẹẹ
si ni ẹsẹ ẹ
ko yẹ
lati dije fun ipo aarẹ to n bọ lọdun 2019. O ni lati
nnkan bii oṣu
meji sẹyin,
lo ni ọkunrin
naa ti n rin irinajo kaakiri orilẹ-ede yii lati fi
ipinnu ẹ
han.
O ni titi di akoko yii lawọn alatilẹyin ẹ ṣi n fi
ifẹ
wọn
han si i pe
ko maa niṣo o,
awọn
wa lẹyin ẹ nibi
ibo pamari ti yoo kọkọ waye. Ileeṣẹ
olupolongo naa wa ke si awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP pe ki wọn fọkanbalẹ ki wọn maa jẹ kawọn onisọkusọ ba
ero ọkan
wọn
je. Idaniloju si wa pe lọdun to n bọ Atiku ni yoo di
aarẹ
orileede
yii.