Pakopako lawon ore meta kan ti won
ni won ko nise meji ju igbo tita lo n wo nigba towo olopaa ipinle Ogun te won
lojo Wesde ose to koja lohun ni opopona ilu Benin siluu Sagamu.
Awon meteeta |
Frank Osai, eni odun
mokandinlogoji(39); Elvis Okuse, eni odun meedogun(25) ati Kelvin Ogagaoghene
toun je omodun merinlelogun (24) lawon odaran naa, ko da a, ta a tun gbo pe
awon ni won maa n ran lati gbe ohun ija oloro lo lati ilu Benin si Eko.
Gege ba a se gbo, ko din ni ogoji
baagi to je pe igbo bii Nicotin, Marijuana atawon min in lo kun inu e ni won
gba lowo won lakoo towo te won, ti won si n bebe pe ki won se won jeje.
Ohun ta a gbo pe ni pe iluu Benin ni
won ti n ko awon eru naa lo si niluu Eko ko too di pe awon olopaa SARS loo dena
de wpn, lati rowo to won.
Nigba to n fidi isele naa mule,
agbenuso fawon olopaa ipinle Ogun, Abimbola Oyeyemi so pe iroyin naa ti te won
lowo tipe, tawon si ti n so won. Sugbon nigba towo palaba won maa segi, se lawon
tun gburo won lojo Wesde naa, tawon si ta awon olopaa SARS lolobo.
Yato si awon igbo ti won gba lowo
won yii, awon olopaa tun gba tirela nla ti nomba idanimo e je KPP 339 XD, iyen
tirela ti won ka Igbo naa mo lowo won.
Oyeyemi so pe nigba tawon eeyan naa
n ka boroboro ni won jewoo pe onibaara won kan yo n je Uche lawon fe e lo ko
won fun l'Eko.
O fi kun un pe Ahmed Iliyasu to je
ogba won ti pase pe kawpn SARS si ko won pamo sogba won digba ti iwadii ipinle
yoo fi pari. Bee lo so pe won gbodo loo mu Uche atawon to tun mo nipa ise
buruku naa.