Tani kii se pe awon olopaa SARS
ipinle Ogun lo ogbon igbalode lati rowo to awon adigunjale kan ti won je
Fulani, ti won so pe won ko nise meji ti won n se ju ki won maa fipa gba maalu,
ki won si maa ji awon eeyan gbe beere owo lo.
Awon mejeeji |
Gege ba a se gbo, won ni awon
adigunjale yi ko ni ofiisi, bee ni won ko mo ara won soju daadaa, sugbon won ni
bi won se n pade ara won, leyin ti won ti fi adehun sibi ti won ba ti fe e
gbera loo sise ibi won.
Lojo Tusde, ojo kerinlelogun osu to koja nigba ti
Ahmed Iliyasu to je Komisana olopaa ipinle Ogun n foju meta lara awon odaran
naa towo te, iyen Audu Isa, omodun marundinlogbon (25), Yusuf Abdullahi omodun
metadinlogoji (37) ati Ali Mohammed ti won loun wa losibitu nibi to ti n gba
itoju pelu oku Abdullahi Nigar han fawon oniroyin ninu ogba oluleese won to wa
ji Eleweran, Abeokuta lo ti so pe o ti pe tawon ti n dode awon odaran naa.
Nigba to n so bawon se ri won mu,
oga awon SARS, Adams Ubah nigba to n b'AWIKONKO soro so pe o ti pe firoyin naa
ti te won lowo, tawon si loo n duro sibi ti won n ko ibon si, bo tile je pe
awon ko mo ibe, sugbon agbegbe naa lawon wa fun bii ose meta.
O lawon odaran naa so awon titi fun
opolopo ojo, ti won si mo igba tawon ma n kuro nibe lati loo sinmi, o so pe
laarin oogun iseju tawon fi maa n kuro nibe lawon odaran naa loo sare ko ibon
won kuro, tawon ko si mo igba.
Ubah Adams so pe bi iroyin tun se
kan si won lawon sese loo pade won nibi ti won ti n mura lati loo ji awon
onisowo nla meji kan, Alaaji Shehu ati Alaaji Kabiru gbe, ki won si tun gba
maalu won salo.
Nigba to n fi fidio ti won ya lati
ibi ti won n ko ibon si ninu moto legbe ilekun ati ninu enjiini moto kasiri won
ma baa tu sawon olopaa lowo han AWIKONKO, Ubah ni ara lo ru awon tawon fi bere
sii beere ibi ti ibon won wa lowo won.
O so pe bawon se ri won ni won ti
bere sii yinbon fawon, tawon naa si koju won, toro bi boolo o yago lona. Nigba
yo n so bi won se pa Abdullahi Nigar, o loun gan an lo lewaju won, ati pe nigba
to ri bi nnkan se n lo si, lo ju ibon owo e sile, to si loo fo mo SARS kan
lorun lati gba ibon owo e.
Igba tawon SARS toku rii ninwon
dabon boo daadaa titi to fi ku, nigba tawon si ye ara e wo, lawon ri gbekude
orisirisi to so mo ara e.
Bo tile je pe ohun ta a koko gbo ni
pe Boko Haram lawon ajinigbe odaran naa, sugbon Audu nigba to n soro so pe awon
kii se Boko Haram sugbon awon kose mose nipa ijinigbe daadaa, ti ko si seni
tawon ko le ji gbe beere owo lowo awon molebi won.
Audu so pe aimoye igba lawon ti ji
eeyan gbe, tawon si ti gba milionu merin lowo enikan rii, kawon to o fi sile,
ati pe eleekerin re e toun yoo ji eeyan gbe lasiri to o tu. O tun so pe maalu
loun n da tele, ki won too pe oun sinu egbe ajinigbe, toun si ri pe owo wa
nibe.
Nigba toun naa n soro, Yusuf to so
pe omo bibi Kwara loun ni maalu ti won ba jibgbe loun maa n ra ta lagbegbe
Obada-Oko, Abeokuta, sugbon lai pe yi ni won foju oun mo ona ajinigbe.
Yusuf ni tiẹ to ni ọmọ ijọba ibilẹ
Asa, ni Kwara, loun, ṣalaye pe Ọbada-Oko, l’Abẹokuta, loun ti n ta maaluu tẹlẹ,
oun maa n ra maaluu mi-in to jẹ wọn ji wọn gbe wa ni, oun yoo si ta a.
Nigba toun naa n soro, Ahmed Iliyasu
so pe ojo kejila osu yi ni won ta won lolobo, toun si pase pe kawon SARS loo
dena de won, sugbon tawon naa ko mu oro naa ni kekere fun won, sugbon towo pada
te won.
Iliyasu ro awon araalu pe bi won ba
kofiri eni to ni ogbe ota ibon lara, ki won ma se le eni naa danu, dipo bee, ki
won tewo gba a, ki won si tete tawon olopaa lolobo.
Bee lo so pe oun ko tii setan lati
gba awon odaran laye nipinle Ogun toun wa, nitori pe awon ko le koo gbe papo.
Bakan naa lo so pe asiko re e fawon araalu, lati sun lorun asundokan.