Ka ni kii se pe awon
omo egbe ojulalakan fi n sori tijoba apapo, iyen VGN tete de agbegbe Lafenwa
nibi ti won ti ranse pe won pe awon odaran meji kan ti n tu awon eya ara moto
onimoto ni, o see se kawon odaran naa ti na papa bora ki won to o de be.
Ohun ta a gbo ni pe
Ibrahim Bamidele, omo ogun odun (20) ati ore e, Babatunde Ahmed toun je omodun
merindinlogun (16) ko nise meji min in ti n won n se ju irin ti won n sa ta
kaakiri lo, iyen ise Bolar.
Yato si pe won n sa
irin kaakiri ori akitan atawon adugbo, won ni won tun maa n ji irin tu, yala
lara ile, tabi nibi ti won ba ko o si lo, bee ni won tun n tipase e ji dukia
oni-dukia gbe salo, sugbon tasiri won pada tu lojo Sande ose to koja yi.
Gege ba a se gbo, okan
lara awon moto ti agbara gbe lo lasiko isele omiyale to sele niluu Abeokuta losu
meji seyin ni moto naa ti won ni jiipu Toyota ti nomba idanimo e je JJJ 522 CJ
ni.
A gbo pe ni nnkan bi
aago mejila koja iseju meedogun (12:15pm) lowo te won, won si ti tu taya meji
lese moto naa, inu e nu won n tu lowo kasiri won too tu.
Okan lara awon to n
koja lo lagbegbe naa lo ta awon Fijilante lolobo, tawon naa si sare gbera lo
sibe.
Nigba to n fidi isele
naa mule f'AWIKONKO, Ogbeni Osualu Jimoh to je oga agba leka amuseya
Fijilante so pe bo tile je pe awon meje ni won n tu moto naa lowo nigba tawon
de be, sibe, owo pada te meji lara won, nigba tawon merin to ku salo.
O je ko di mi mo pe
lesekese lawon ti sewadi eni to ni jiipu naa, iyrn Arabinrin Eniola Alabi to n
gbe ni ojule ketadinlogbon, adugbo Muraina, Shoyode, Lafenwa, tawon si ti ba a
soro.
Obinrin naa nigba to n
b'WIKONKO soro, o nidii toun ko ti rii gbe moto naa kuro layigba yi
agbara ti gbe e lo ni ti iranlowo ijoba toun n reti, nitori pe ko tii sowo toun
yoo fi gbe lowo oun, depodepo owo toun yoo fi tun un se.