OJUDE OBA: AREWA OBINRIN DI AWATI - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, August 31, 2018

OJUDE OBA: AREWA OBINRIN DI AWATI

Titi di bi e ti n ka iroyin yi, iyalenu loro odomobinrin arewa kan ti won pe oruko e ni Mariam Ayelotan, eni ti won ni lati ose to koja yi to ti jade ni ko ti pada wole mo.


Ayeye olodoodun ti Ojude Oba to waye niluu Ijebu Ode lojo Tosde ose to koja yi ni won so pe Mariam dagbere ko too kuro nile, latigba naa ni ko ti senikeni to gburo e.


Okan lara awon ore egbon e lo gbe iroyin naa sori ero ayelujara Layi fi to gbogbo eeyan leti pe enikeni to ba ba won ri Mariam, ko tete fi to awon leti.


Bawon kan se n so pe o see ki odomobinrin arewa naa ti tele awon omo jayejaye ti won n fi ise Yahoo boju jaye lo, ki won si ti loo fi soogun owo, bee lawon kan n so pe afaimo ko ma je pe awon kan ni won jii gbe salo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI