Bo tile je pe AWIKONKO ko tii le fidi ojo ti ayeye Ojude Oba olodoodun to maa n waye niluu Ijebu-Ode laarin ojo ketalelogun ati ojo kerinlelogun osu yi, sibe ohun ta a gbo ni pe gbogbo eto lo ti fe e pari bayii fun ti ayeye naa.
Ojo meji leyin ayeye odun Ileya ni ayeye Ojude Oba yoo waye, gege ba a se gbo.
Iroyin to te AWIKONKO lowo lai pe yi so pe, ojo Aje Monde to koja yi ni ileese GLOBACOM to maa n sagbateru ayeye naa lodoodun se ipade awon oniroyin lori ipalemo eto ayeye naa, nibe ni won ti je ko di mi mo nipa awon ipinu won fun ayeye todun yii.
Nibe ni awon agbaagba niluu Ijebu Ode to fi mo awon igbimo ti won yan lati dari ayeye todun yi, ti Otunba Wahab Osinusi je alaga won ti sepade papo lati jiroro pelu awon alase ati oludari ileese Globacom.
A gbo pe akori ti won fun ayeye todun ni "Ojude Oba: Gbigbe Asa Ajogunba Laruge", iyen ni pe “Ojude Oba: Celebration of Rich Cultural Heritage”.
Oludari eka ipolowo ati ikansiraeni lekun ipinle Eko ati Ogun (Globacom Marketing and Communications Head, Lagos/Ogun Region) Ogbeni Afolabi Otufowora nigba to n soro gboriyin fun Awujale tile Ijebu, Oba Sikirulai Adetona fun akitiyan e lati maa fowosowopo pelu awon omo Ijebu nipa gbigbe Asa won laruge lodoodun.
Otufowora so pe ko je nnkan to pon ilu le lati gba ki olaju ba awon Asa atijo wa je, nitori naa lawon yoo se maa tubo gbaruku iru awon ayeye bii ti Ojude Oba yii.
O bu enu ate lu owo tawon eeyan paapaa awon odo fi n mu igbelarujge asa, to si gba won nimoran pe ki won maa fi idunnu won han sawon asa ajogunba won, nitori pe ebun nla lo je.
Ninu oro ti e, alaga igbimo ayeye naa, Otunba Wahab Osinusi so pe igbese ti n lo pelu ajosepo ijoba ipinle Ogun lati rii pe won mu todun yi lokunkundun daadaa ju ti tele lo.
Bee la tun gbo pe Aare ile igbimo asofin agba niluu Abuja, Seneto Bukola Saraki yoo wa nibi ayeye todun yi fun igba akoko.
No comments:
Post a Comment