...Won ni ko tii pe osu
kan to ko de ile to ti ji omo gbe
Titi di bi e se n ka
iroyin yin, lawon araadugbo Ajaka to wa niluu Sagamu si n gbe Arabinrin kan ti
won pe oruko e ni Precious se epe rabande-rabande latari bi won se loo ko meji
ninu awon omo ayalegbe egbe e jade kuro nile, ti ko si tii ko won pada di bi e
se n ka iroyin yi.
Gege bawon to firoyin
naa to AWIKONKO leti lojo Tosde ose to koja yi se so, ojule kerin, opopona
Adetayo, Ajaka niluu Sagamu ni won so pe Ogbeni Sunday Ajayi, iyawo e,
Arabinrin Yemisi Ajayi ti won ji meji ninu omo won gbe lo, ti won ko si tii ri
won titi dasiko ta a sakojopo iroyin yi tan.
AWIKONKO gbo pe ojo
Tusde, ojo kerinlelogun osu keje to koja yi ni won so pe Yemisi lo sibi ayeye ikekoo jade ti won se
nileewe awon akobi omo e ti won loun naa sese pari ileewe alakobere ni.
Asiko naa ni won so pe
Precious ti won lomo ile Yibo ni ko awon omo meji ti Yemisi ati oko e, Sunday
bi ti won fi sile sile jade lo, ti ko si dagbere fenikeni, to si je pe latigba
naa ni won ti n wa won, yi won ko si tii ri won titi ta a fi sakojopo iroyin yi
tan.
Bo tile je pe orisirisi
lawon araadugbo naa, paapaa awon ti won jo n gbe inu ile naa so nipa Precious
ati baba onile naa, Ogbeni Seyi Oguntade, eni ti won loo ti wa lahamo awon
olopaa lati ojo Wesde titi dasiko yi, sibe a gbo pe gbomogbomo ni Precious.
Bawon kan se n so pe
baba onile naa, Ogbeni Oguntade mo nipa ibi ti Precious ko awon omo naa ti won
poruko wpn ni, Ayobami to je omodun mefa ati Temidayo toun je omodun merin lo,
bee lawon kan n so pe ko le mo nipa e.
Lara awon araale naa to
b'AWIKONKO soro, iyen awpn ti won so pe ka foruko bo awon lasiri so pe ko tii
yo.osu kan ti Precious ko de ile naa, ati pe ojo merin gbako ni Precious fi sun
yara Seyi to je baba onile, tawon mejeeji si n se wole-wode.
Yara Precious |
A gbo pe Seyi ko gba
owo to ye ki Precious san gege bi owo ile pe lowo e, won ni egberun
marundinlogbon (25,000) naira lo san ninu owo odun to ye ko san, to si je pe
ojo to ko de ile naa lo ti bere sii sun ninu yara Seyi fungba tiyawo e ko fi si
nile.
Ohun tawon kan n so ni
pe aale baba onile ni, ati pe gbogbo igba ti Precious fi sun yara baba onile
naa ni won fi n ba ara won sun, ti ko si senikeni lo le ba won soro nigba to je
pe se lawon naa ya ile gbe nibe ni.
Bee la gbo pe ko seni
to mo ibi ti Precious ti wa, ti won ko si mo awon eeyan e kankan, sugbon nkan
to da won loju ni pe omo Yibo ni.
Ojo Wesde ojo keji ti
won loo foro naa to awon olopaa leti la gbo pe won gbe baba onile naa, to si je
pe tesan olopaa lo wa titi ta a fi sakojopo iroyin yin tan, tawon olopaa ko si
tii je ka rii ba soro.
Nigba to n b'AWIKONKO
soro pelu iporuru okan, Arabinrin Yemisi Ajayi to loko oun ko si nile je ko ye
wa pe korofo lo wa ninu yara Precious nigba tawon wonu e, ati pe baagi kekere
kan lawon ri nibe.
Yemisi so pe "Omo
merin pere ni mo bi, akobi mi lo n sayeye ikekoo jade nileewe ti mo si lo sibe,
mi o ko awon aburo won meji dani. Igba ti mo kuro nibe ti mo pada de ile, mo
beere pe nibo lawon omo mi wa, awon araale so fun mi pe Precious ti ko won jade
loo sere, igba to di irole ni nnkan bi aago marun aabo, ti mi o ri won leru ti
bere sii ba mi, ti ara n fu mi.
"Ko seni to sun
moju ninu ile wa, nitori pe ironu awon omo naa ti da nnkan ru, ekun ni mo n
sun. Ko sibi ti a o wa won de lojo keji, awon kan tun gba wa nimoran pe ko sile
awon 'yemiwo', ta a si ko foto won lo sibe. A tun ti loo foro naa to awon
olopaa leti, sugbon to je pe pabo lo n ja si."
"Ko tii pe osu kan
ti Precious ko de ile yi, Iyawo la maa n pe , bo tile je pe a o mo boya o ti
l'oko ri, sugbon ojo ori e a ti to bii odun marundinlogoji (35). Gbogbo ba a se
n pe nomba e ni ko lo, o ti pa a.
Nkan to to ti e
maa n ya wa lenu ni pe kii silekun e sile lati je keeyan wo yara e, sugbon o
feran lati maa wo yara-oni-yara.
"Kii se pe a maa n
fi omo wa sile fun un, sugbon o maa n bawon Omo sere, o si maa n gbe won jade
lo ra nnkan fun won. Mi o ti e mo nnkan ti mo fe e se mo bayii, a fi kijoba ran
mi lowo lati ba mi wa awon omo mi, ko ma ti e lo fi won soogun owo."
Arabinrin Ayo Oguntade
to so pe iyawo baba onile loun, eni to niluu Eko koun n gbe nigba to n b'AWIKONKO
soro so pe bi tile je pe oun kii saba a gbe ile naa, sugbon oun jeri oko oun pe
kii se alagbere, to le maa ba Precious sun, won kan fe e ba loruje lasan ni.
O lawon ayalegbe won ni
ko kiyesara, ti won n fawon omo won le fun Precious, tiyen fi raaye da won lori
ru, ti son si gba a gbo. Bre lo so pe ko seni to ko de ile naa ti kii gba
foomu, sugbon oun ko le so boya Precious gba foomu ni ti e.
Iyalenu lo je fun wa
nigba ti won silekun yara Precious fun wa, to je pe ko si eru kankan nibe,
ayafi baagi ofifo kan, ati kapeeti to te sile lasan lo ww ninu yara naa.
Nigba toun naa b'AWIKONKO
soro boya o ti gbo sii, agbenuso fawon olopaa, Abimbola Oyeyemi so pe oun ko
tii gbo nnkan to jo bee, ati pe oun nigbagbo pe iwadii ti bere to ba je otito
ni, tawon yoo si mu odaran naa lai pe.