Titi digba ta a sokojopo iroyin yi
tan, inu idaamu ati ibanuje okan ni molebi Obadeyi wa latari bi won se lu omo
won Damilare Obadeyi loruka, ti oruka naa si je ti warapa, gege ba a se gbo.
Damilare |
Ohun ta a gbo ni pe ni nnkan bi aago
meje aabo ale ojo Monde ose to koja yii ni Damilare atawon ore e lo sile tete
ti igbalode kan, iyen Naija Bet tawon odo asiko yi nta ladugbo Ago-Oba, Abeokuta,
ibe la gbo pe Damilare ti je owo ti ko din egberun mejo (8,000) naira.
Bi ariwo owo ti Damilare je yi se
kan sita, lawon ore e ti bere sii kii ku oriire, ti won si n beere pe ko fun
awon naa ninu e, sugbon ti won loo yari pe oun ko le fenikeni nitori toun naa
ni nnkan toun fe e fowo se.
Ere ni won pe e, a fi bi won se
lawon kan so oro naa dija mon on lowo, toro naa si di isu ata yan-an-yan-an.
Nibe la gbo pe okan lara awon ore e to fe e fi tipatipa gba owo lowo Damilare,
iyen Saheed Gafari ti yo oruka lapo.
Awon to fisele naa to AWIKONKO leti
nirole ojo Tusde, iyen ojo keji isele naa je ko di mi mo pe awon ko mo pe oruka
warapa ni Saheed yo lapo, nitori tawon ro pe o kan fe e fi seruba Damilare
lasan ni, nitori pe ore ni won, a fi bo se fi gba a.
Won ni se ni Damilare daku nigba ti
Saheed fi oruka naa gba, osibitu ibile kan ti won sare gbe e lo lo laju sii ni
nnkan bi aago meta oru ojo keji.
Nigba to n b'AWIKONKO soro,
Arabinrin Marian Obadeyi to loun ni mama Damilare, o so pe oun ko tete gbo nipa
isele naa, sugbon nigba toun de ile iya baba Damilare, Nibe loun ti ba ero
repete.
Italenu ni Marian loo je foun,
paapaa nigba ti won gbe oro naa soun leti pe won gba Damilare loruka, to si n
po foomu funfun lenu. Obinrin naa so pe titi ti omo oun fi laju loru ojo keji
lo si fi n po foomu naa lenu, iyen ti Dokita tawon gbe e lo sodo e, iyen Dokita
Dauda Eweje ti bere itoju fun.
O tesiwaju pe, bo tile je pe oun ko si
nibe lasiko isele naa, sibe awon ore Damilare min in bii Rado, TMS fidi e mule
foun pe Saheed lo luu loruka, tawon si ti n wa a kaakiri ko le fun un ni ero e,
nitori ti won so pe bi won ko ba tete fun un ni ero e, odoodun ni yo maa so o
wo.
Bee lo tun fi kun oro e pe o see se
ko je pe owo baba Rado ni Saheed ti loo gba oruka naa, nitori to so pe babalawo
ni baba Rado, ati pe gbogbo won lo ti na papa bora latigva ti wahala naa ti
feju sii.
Lati fidi isele naa mule siwaju sii,
AWIKONKO gbera dele Saheed ti won juwe fun wa, nigba ta a beere Saheed, won ni
ko seni to le so ibi to lo nitori ti ko wale lati ale Monde, bee ni won so pe
Iya Sahees naa ko sunle lati gba naa, ati pe aaro kutu Tusde lo ji wa sile, to
si tun jade pada lai dagbere fenikeni.
Nigba to n fi inira soro lori beedi
osibitu to wa, Damilare to ni ise alumi loun n s e so pe oun ati Saheed ti nija
ara won sinu tipetipe tele rii.
O so pe kii se pe oun ko fe e fi
ninunowo naa sile, nitori toun kan fe e wo bu yoo se ri lara awon ore oun to wa
nibe, sugbon kayeefi lo je foun bi Saheed se gbe oro naa, to si gba a sagidi
foun.
Damilare so pe ere loun koko pe e, a
fi bi Saheed se bere sii tan ina toosi (tourch light) soun loju, to si tun
ranse pe awon toogi ore e, ti won si bere sii lu oun bii pe won ko mo oun ri
rara tele.
Dokita |
Ninu oro e, o so pe "Won lu mi
gan an, ibi ti won ti n lu mi lowo ni mo ti sakiyesi pe enikan ninu won fi irin
bi oruka gba mi, nive ni monti subu sile, ti mi o si mo njkan to n sele mo.
Igba ti mo maa laju ni mo ri ara mi lori beedi nibi.
"Bi mo se wa yii, mi o le gbe
ara mi di de, mi o le jeun, ebi n pa mi. Won so pe a fi ti a ba ri Saheed lati
fun mi ni ero nnkan to fi lu mi ki ara mi to o ya daadaa, ati pe won tun so pe
gbogbo ojo ketala odoodun ni warapa ma maa gbe mi. E gba mi o."
Lati fidi e mule pe looto ni oruka
naa je ti warapa, ati pe lodoodun ni yoo maa so o wo, AWIKONKO ba Oloye Dauda
Eweje, iyen Dokita to n toju Damilare soro, o so pe looto ni, ayafi ti won ba
ri ero e fun.
Oloye Eweje to tun je Aragberi Onisegun
Egba tun so pe "Oruka warapa ni won n pe ohun ti won fi gba Damilare,
efuufu to n jade lenu Damilare nigba ti won gbe e de, ohun to to pa oro oruka
naa lawọn lo fun un to si fi farabale bee.
"Sugbon saa, ki Damilare to o
le gbadun daadaa ti kinni naa ko ni i maa so o wo lodoodun, mo gbodo ri eni to
lu u loruka naa lati beere oro lowo e. Yo ba je pe se ni eni naa salo patapata,
ona kan to seku naa ni pe baba Dare gbodo yoju, yoo si setan lati nawo gidi,
nigba naa ni yoo too le se gbogbo ohun ti yoo mu komo re gbadun."
Ojo Wesde la tun gbiyanju lati
sewadi siwaju sii, sibe pabo ni iwadi naa ja si. Awon to b'AWIKONKO soro je ko
di mi mo pe Damilare funra e kii se eran to to, o kan je pe oun kii yo nnkan
ija oloro bii igo, obe tabi ada bi inu ba ti n bii.
Sibe, titi ta a fi sakojopo iroyin
yi tan, won ko tii ri Saheed, Rado, TMS ati Shoe Get Size ti won so pe.omo egbe
kan naa ni won, bee la gbo pe won ti loo foro naa to awon olopaa leti lati ba
won da sii.