Titi di bi e ti n ka iroyin yi, inu idunnu ati ayo ni molebi Gbeleyi wa, ti won si n sayeye ojo ibi odun mejilelaadota ti Arabinrin Joyce Gbeleyi se lojo Fraide to koja yii.
Fawon ti ko ba mo Arabinrin Joyce Gbeleyi, ohun ni iyawo amugbalegbe gomina ipinle Ogun lori oro ina ati alakoso TCN nipinle Ogun, iyen Onarebu Olusegun Bolanle Gbeleyi.
Ilu Manchester United lorileede United Kingdom ti obinrin naa atawon omo won n gbe ni ayeye ojo ibi naa ti waye, nibe lawon ololufe e won ti loo ba won yo ayo naa.
Gege bi a se gbo, iyalenu lo je fun Arabinrin Joyce Gbeleyi nigba to ri oko e, to de lojiji si Manchester United, nitori ti ko ro o tii tele.
Nigba to n ba akoroyin kan to gbe iroyin naa si AWIKONKO leti soro, Onarebu Gbeleyi sapejuwe iyawo e gege bi eni to ni iteriba, iberu Olorun ati ife lokan, idi ni yii to fi loun ko le salai ma yoju sii lojo ayo e.
O ni boun ba tun ni nnkan min in toun tun le se fun iyawo oun lati mu inu e dun siwaju sii, oun yoo se e, nitori pe o to bee, o ju be e lo.
No comments:
Post a Comment