IYAALE ILE TO JI ARA E GBE LATI GBA MILIONU MEEDOYBON LOWO OKO E DERO ATIMOLE - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, August 22, 2018

IYAALE ILE TO JI ARA E GBE LATI GBA MILIONU MEEDOYBON LOWO OKO E DERO ATIMOLE


"E saanu mi, e ma je ki n sewon" lorin ebe ti iyaale ile eni odun marundinlaadota (45) kan, Adijat Kabir n ko ni tesan olopaa ipinle Eko lojo Sande ose to koja yi nigba tasiri e tu pe oun gan an lo loo ledi apo papo pelu awon kan ti won jii gbe lati fi gba owo ti ko din ni milionu meedogun (15) naira.

Gege ba a se gbo, won ni Adijat ti won loo larun opolo die ni won loo ranse pe awon kan ti won ko nise meji ju ise ajinigbe lo pe ki won ji oun gbe, koun si le baa ri owo nla gba lowo oko oun.

Asiko ti won ni omo Adijat ti won poruko e ni Hamidat toun je omodun mejidinlogun (18) n tele e lo si osibitu ti won ti n se itoju awon to ni aarun opolo, eyi to wa lagbegbe Oshodi niluu Eko lawon eeyan naa dena de won, ti won si gbe won salo, iyen lose to lo lohun.

Latigba naa la gbo pe won ti bere sii pe foonu oko Adijat, iyen Muraino Kabir pe bi ko ba tete wa a san milionu meedogun naira, awon ko nii fi iyawo ati omo e sile, tawon yoo si tun pa won danu fun un.

Oro idunkoko yi gan lo je ki Muraino gba tesan olopaa to wa ni Ikotun lo lati loo fi to won leti, tawon yen naa si bere igbese lati topinpin won.

Nigba tasiri maa tu pelu imo igbalode ti won lo, won sakiyesi pe lagbegbe kan niluu Ado-Odo Ota lawon eeyan naa wa, ti won si loo lati loo mu won.

Bi lara awon eeyan naa se rii pe asiri awon ti tu sawon olopaa lowo no won ti na papa bora, sugbon towo pada te die lara won.

Nibi ti won ti n ka boroboro ni won ti so pe Adijat lo gbe ise naa fawon lati le gba owo lowo oko e, ati pe awon naa nilo owo lo ke kawon tete gbe igbese naa.

Adijat ninu oro ti e so pe looto ni, ati pe kani oun mo pe asiri maa pada tu ni, oun ki ba ma ti gbe igbese naa rara, nitori naa ki won wo ti ipo ailera toun wa lati ma je koun sewon osan gangan.

PÍN-IN KÁÀKIRI