Ariwo ikunle abiyamo lo gba eni awon
ara lagbegbe Owode Ijako lojo Wesde ojo kinni in osu yi nigba ti oko boosi
akero kan loo kolu olokada kan, to si te e pa raurau.
Oku kan re e |
Gbogbo awon tisele naa soju won ni
ko si le gbagbe bisele naa se waye, paapaa bo se je pe olokada naa ti won
nibise e lo n lo sagbako iku ojiji yii.
A gbo pe oko akero boosi to ni aawo
ilu Eko, iyen Varagon ni won so pe ere asapajude to n ba bo lo fi loo gba
olokada naa danu lasiko to fe e de ibi ti gosilo (go-slow) wa.
Won ni lesekese ni awqko naa ti
salo, ti ko duro wo oku eni to pa, sugbon to je pe awon eso oju popona tijoba
ipinle Ogun ni won pada le e mu, ti won si rii mu lagbegbe Sango, sibe, a gbo
pe awako naa tun ri aaye salo.
Awon TRACE la gbo pe won pada gbe
oku okunrin naa lo si mosuari osibitu jenera to wa ni Ifo, bee ni won gbe boosi
naa lo sinu ogba won.
Ijamba keji la gbo pe lagbegbe
Saapade lo ti sele nigba ti won so pe oko ayokele Hyundai ti nomba idanimo e je
KJA 256 CK lo so ijanu e nu, to si sare wo abe tirela ti won paaki segbe titi.
Agbenuso fawon osise TRACE, Ogbeni
Babatunde Akinbiyi to fidi iaele naa mule je ko di mi mo pe eeyan meta lo wa
ninu moto naa, to si je pe eeyan kan soso lo dagbere Faye, nigba tawon mejo to
ku farapa yannayanna.
Mosuari osibitu jenere to wa niluu
Isara la gbo pe won gbe oku obinrin to ku sonu ijamba naa lo, tawon meji to ku
si wa ni yara ti won ti n toju awon to nisele pajawiri, nibi ti won ti n gba
itoju.