EYI NI BI BABA AGBALAGBA SE POKUNSO L'OGUN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, August 22, 2018

EYI NI BI BABA AGBALAGBA SE POKUNSO L'OGUN


Titi di bi e ti n ka iroyin yi lori baba agbalagba eni odun mokandinlogota (59) kan, Oloogbe Adewale Majekolagbe to pokunso lojo Tusde ose to koja yi si n je fawon ara agbegbe Ibafo, paapaa awon to gbo nipa isele aburu naa.

Ko si nnkan meji to n ya awon eeyan lenu bi ko se ti leta ti won ni baba naa ko sile ko to o jade laye, to si je ko di mi mo pe nitori omo oun, Ayoku loun se pa ara oun lati loo sinmi.

Gege ba a se gbo, adugbo ti won fi oruko baba so, iyen Majekolagbe, Ereko Estate, Ibafo nisele aburu to ya opo eeyan lenu naa ti waye.

Ohun ta a gbo ni pe lati osan ojo Tusde ni won ko ti ri baba naa ti won so pe ojo ketadinlogbon (27) osu kewaa odun nu yoo pe ogota odun, gbogbo bi won se n pe e lori foonu ni ko gbe.

Awon to mo Oloogbe Adewale gege bo se maa n se nigba ti won ko ri lo mu ki won maa fura pe nnkan ti n sele, idi ni yii to fi je nigba to di aaro kutu ojo Wesde, se ni won loo fipa ja ilekun le ti baba naa n da gbe.

Ariwo ikunle abiyamo lo gba enu awon eeyan kan nigba ti won ri bi baba agba naa se n mi jolonjolo lori oke to so ara e ko sii, loju ese ni won ti ranse sawon olopaa lati wa a wo nnkan to n sele ladugbo won.

Nnkan pataki to tun je kawon eeyan maa banuje nipa bi baba naa se gbemi ara e ni ti leta ti won loo ko sile ko too pokunso, to si je ko di mi mo pe nitori omo oun to n je Ayoku loun se gbemi ara oun nitori pe wahala to n fojoojumo ko oun si po ju agbara oun lo.

Inu yara iyawo e to ti doloogbe la gbo pe Adewale ti won ni ko nise gidi lowo pokunso sii. Worobo ti won n iyawo e n ta ko too ku ni baba naa n ta, ti igba si ti joro tan latari gbese ojoojumo to n san.

AWIKONKO gbo pe gbogbo igba ni Ayoku maa n lo je gbese kaakiri adugbo, ti yoo si je pe baba yi lo maa ba a san gbese naa, ko da a ta a gbo pe o ti figba kan loo je gbese milionu kan naira ri, to je pe baba naa lo ran owo san.

Lara awon to b'AWIKONKO soro lojo Tosde ta a yoju sibe je ko ye wa pe ori wahala Ayoku yi ni iyawo baba yi ku si lodun meji seyin, aisan ropa-rose, iyen sirooki lo pada gbemi mama naa.

AWIKONKO gbo pe nigba tawon olopaa de ni won too sese ja oku baba naa bo lati oke to wa, bi won si se fe e gbe e lo si mosuari lawon lanloodu adugbo naa ko gba fun won, idi ni pe won ni ayafi tawon omo e ba de ni won to o le so igbese to kan.

Idi ni yii ti won lawon olopaa fi pada lo senu ise won ni nnkan bi aago mejila ku iseju meedogun aaro Wesde, sugbon nigba ti won ni awon omo baba naa de, paapaa omo e kan to n gbe Abeokuta de ni won too sese sin in siwaju ita ile e nirole Wesde.

A gbo pe ko seni to fisele naa to Ayoku leti ko too di pe o yoju sile lojo naa, igba to si de, se lawon eeyan dawo jo, ti won si bere sii luu to di pe won ja sihoho lai tii mo nnkan toun se rara, awon majeobaje adugbo naa ni won pada gba a sile.

Nigba ti won fi sile ni won to o so nnkan to sele fun un ti won loun naa bere sii sunkun bi egbere.

Won niwaju ita ile baba naa lawon eeyan ti maa n sere gbategun lati aaro di owo ale, to ba si ti n di bi aago mejo ni baba ti won ni ko nise gidi lowo yi maa lo sile ore e kan lati loo sere di bi aago mejila ko too pada loo sun.

A ti e tun gbo pe ojo Monde kisele naa to o waye ni Adewale ti fe loo ya egberun lona aadota (50,000) naira, gbese ti Ayoku je ni won loun fee fi san, sugbon ti ko ri owo naa ya.

Bee ni won tun je ko ye pe ori gbese ti Ayoku, omo e je kaakiri ni Adewale ta moto kan soso to n lo tele sii lodun to koja. Bakan naa la tun gbo pe Ayoku naa ko nise gidi lowo, ti ko si seni to mo idi to fi n je gbese kaakiri.


PÍN-IN KÁÀKIRI