BI ODO BA FE E GBAJOBA, A FI KI WON FI ARA WON JIN FUN OSELU - PASEDA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, August 13, 2018

BI ODO BA FE E GBAJOBA, A FI KI WON FI ARA WON JIN FUN OSELU - PASEDA

Okan lara awon adije sipo gomina ipinle Ogun lodun 2019, Otunba Olarotimi Olatunde Paseda ti gba awon odo orileede Naijiria lamoran pe ki won fi ara won jin fun oselu lati le je kawon naa je asiwaju ninu eto isejo.


Paseda lo soro naa niluu Ijebu-Ode nibi ayeye ayajo ojo awon odo lagbaye to waye lopin ose to koja yii, nibe lo ti so pe bi awon odo ba mo pe looto lawon fe e gba ijoba, a fi ki won fi ara won jin fun oselu, ki won si se e tokan-tokan.

O ni bawon odo ba se kopa si ninu oselu lorileede Naijiria lo maa fun isejo awaarawa lokun ati agbara, eyi ti yoo je ki idagbasoke ati ilosiwaju alailegbe de ba Naijiria.

Bakan naa lo tun ro won pe ki won tete loo gba kaadi idibo alalope, iyen PVC won bi won ba fe e je ki eto ati ipinu to so pe awon odo ko kere lati dari ijoba, iyen Not Too Young To Run.

Bee lo tun gboriyin fun Aare Muhammadu Buhari to bu owo lu ofin pe kawon odo naa kopa ninu eto oselu, atawon to gbe erongba naa kale.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI