“Ise esu ni, ejo mi ko” loro ebe to n jade
lenu bale ile eni odun marundinlaadota (45) kan, Ogbeni Julius Ochim ti won
fesun kan pe o fun omo e tojo ori e ko ju odun mejidinlogun ta a foruko bo
lasiri lo.
Julius |
Gege ba a se gbo, kani omo naa mo tete loo
foro naa to awon olopaa leti ni, o see se ki Julius ti ran an lo sorun
apapandodo latari bi ko se faaye gba lati ni orekunrin, tabi ko maa jade bo se
wuu.
AWIKONKO gbo pe lati odun 2009 tiyawo
Juliu to je iya omo naa ti ku ni Julius ti n ko ibasun fun karakara, ti ko si
gbiyanju lati fe iyawo min in, ko too di pe omo naa loyun mon on lowo ni nnkan
bi odun meta aabo seyin.
Gbogbo bi won ni won se n beere lowo omo naa
pe talo fun un loyun, ni ko jewo fenikeni latari bi won se so pe Julius ti
dunkoko mon on pe se loun yoo pa a danu to ba fi le jewo, tiyen naa si se oro
naa ni iso inu ekuu.
Leyin tomo e naa bimo tan fun un, ti won rii
pe baba omo ko yoju, titi tomo naa fi pe odun meji aabo ni ko seni to fura sii
pe Julius lo fun un loyun to fi bimo obinrin naa.
Ojoojumo la gbo pe Julius ta a ko tii mo ise
to n se titi dasiko ta a sakojopo iroyin yi tan fi n ko ibasun fomo to bi ninu
karakara, tiyen naa ko si reni to le so fun un lati gba a sile lowo odaju
abiyamo baba e.
A gbo pe lati bii odun to koja ni omo naa ti
n so fun baba e pe ko je koun maa lo sile oko, nitori toun ti ri eni toun fe e
fe gege bi oko, sugbon se ni won so pe Julius fariga pe ko saaye fun lati lo
sile oko.
Omo e ati omo-omo e |
Gbogbo bi omo naa se n daamu Julius pe ko je
koun maa lo sile oko, lo n so pe oun ko le fi sile lo fokunrin min in, igba to
ya lo bere sii dunkoko mon on pe to bat un gbe oro so lenu, se loun yoo pa
danu.
Ose meji seyin lomo naa gba tesan olopaa lo lati
loo fejo baba e sun ni tesan olopaa to wa niluu Sagamu.
Bo tile je pe won ni Julius koko paro fawon
olopaa nigba tasiri e tu, sugbon nigba to ya lo pada jewo, to si nbebe fun
idariji pe ise esu ni. Julius nigba to n ro ejo e fawon olopaa so pe atigba
tomo naa ti n tele okunrin min in jade loun ti bere sii nisoro pelu e ninu ile,
ko too di pe o de tesan olopaa.
O ni kii se pe oun ko fe e fi omo naa sile lati
loo fe okunrin min in, sugbon boun ba fi sile lo, ko ni sii aaaye foun mo lati
maa ba a sun, idi niyii toun fi n dunkoko mon on.
Nigba to n jeri soro naa, agbenuso fawon olopaa
ipinle Ogun so pe looto ni ati pe Komisana awon ti pase pe kawon si ti mole
fungba tawon yoo tun fi ri okodoro oro daa daa, eyi ti yoo je gege bi eri fawon
nile ejo, nitori pe lai pe lawon yoo foju e bale ejo.