AYE GBEGE: FELIX JI MOTO EGBON L'ABEOKUTA, LO BA TA A DANU S'EKO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, August 22, 2018

AYE GBEGE: FELIX JI MOTO EGBON L'ABEOKUTA, LO BA TA A DANU S'EKO


…Mo fe e dolowo lojiji ni mo se ji moto naa ta - Felix

Awon agba bo, won ni 'ajumobi ko kan ti aanu, eni abinibi lo n s'eni', won yi loro to lo nibamu pelu bi odomokunrin eni odun metalelogun (23) kan, Felix Goodluck to ji moto egbon e gbe niluu Abeokuta, to si loo ta a danu si agbegbe Ajah niluu Eko.

Goodluck atawon ore e
Ohun ta a gbo ni pe inu osu kefa odun yi ni Felix ji moto boosi Mazda akero naa gbe, nibi ti egbon e ta a ko tii moruko e dasiko ta a sakojopo iroyin yi tan paaki e si.

Bi won ni Felix ti ko nise gidi kan lowo se gbe se moto naa lo ba lo gbe e sibikan, to di pe o n wa onibara fun un, ko ju ose meji lo la gbo pe Felix pade Sodiq Lawal, bo tile je pe won ti mo ara won tele, tiyen si so pe oun yoo maa san owo naa diedie fun un.

Ohun ta a gbo ni pe milionu kan ati egberun lona ogorun (1.1milion) naira ni adehun ti won jo o se, sugbon ti won ni 169,000 lowo ti Sodiq si san fun un pelu adehun pe oun yoo maa san egberun lona ogbon (30,000) losoosu.

AWIKONKO gbo pe ori adehun ni yi ni won wa towo olopaa ipinle Ogun fi te Semiu Mustapha ti won ni Sodiq gbe moto boosi naa fun lati maa fi sise, ko si maa mu owo wa.

Nnkan ti won lo n je kayeefi ni pe gbogbo bi egbon Felix se n wa moto yi kaakiri ni Felix naa n ba a wa a, ti won lo si tun n gba egbon e lorisirisi ona ti won le gba ri moto naa, sugbon a gbo pe Felix ko mo pe egbon e ti loo foro naa to awon olopaa leti.

Agbegbe Ijebu-Ode la gbo pe owo olopaa ti te Semiu pelu moto naa, gbogbo bi won si se n beere nipa ibi to ti ri moto naa lo n so fun won pe Sodiq lo gbe e foun, idi ni yii to fi mu awon olopaa lo sile Sodiq, ti won si mu oun naa.

Nigba to n salaye oro naa f'AWIKONKO lose yo koja, Sodiq ni kani oun mo pe Felix loo ji moto naa gbe ni, oun ko nii ra a lowo e rara, sugbon nnkan to ni Felix so foun ni pe awon obi oun lo ra a moto naa foun lati maa fi sise dipo boun ko se nise lowo, to je pe se lo n fese gbale kaakiri.

Sodiq, omo ogbon odun ni alaye ti Felix se foun nigba maa ni pe oun ko le maa se wahala lati wa moto kaakiri, idi ni yii toun fi fe e ta moto naa lati fi da ise ti ara e sile, tori pe o nise toun fe e se lokan ki won to o ra moto naa foun.

Nigba toun naa n soro, Felix so pe nigba toun ko ri ise se leyin toun jade ileewe girama lodun meta seyin, lo je koun ronu lati ji moto naa gbe lati fi pile oro ati ola oun.

O ni se loro naa yi pada gege boun se ro o nigba to je pe diedie lowo naa n wole, to si je pe bowo naa se n te oun lowo loun n na a je, ko to o di pe won mu Sodiq toun ta a fun in, ti won si wa a mu oun.

Agbenuso fawon olopaa ipinle Ogun, Abimbola Oyeyemi ninu oro ti e so ka ni Felix mo pe asiri eni to ta moto naa fun ti tu ni, o see se ko ti na papa bora nigba ti won ranse pe lori foonu.

O wa a gbawon eeyan lamonran pe ki won sora fawon ti won n foro won lo nitori pe ajumobi ko ko taanu, bee lo so pe kawon to n jeri si agbara Olorun naa mo ona ti won yoo maa gbe e gba nitori pe aye ti gbege ju.

PÍN-IN KÁÀKIRI