Oludije gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu ADP nipinlẹ Eko, Babatunde Ọlalere Gbadamọsi tọpọ mọ si BOG ti sọ pe ijọba Baba sọ pe ti wọn n lo nipinlẹ Eko ti su awọn araalu wọn si ti sun wọn mọ ogiri, idi niyii ti won fi n wa ẹgbẹ oṣelu ti yoo jẹ ọna abayọ nibi ibo to n bọ lọdun 2019 ti yoo le
APC danu.
Babatunde Olalere Gbadamosi |
O sọrọ yii lakooko to
n ba awọn
oniroyin sọrọ nibi ipade tawọn oloye ẹgbẹ ADP nilẹ Yoruba ṣe, eyi to waye
niluu Eko. O sọ pe
ijọba
ti wọn
n lo lati nnkan bi ogun ọdun sẹyin lo ti su awọn eeyan, bo tilẹ jẹ pe o tipẹ ti wọn ti fẹẹ
le wọn
danu ṣugbọn ojooro ati awọn iṣẹ
ibi tawọn
to wa nijọba
naa n ṣe
ko jẹ.
Gbadamọsi sọ pe lọdun 2003, ni wọn ti kọkọ fẹẹ
fi ibo le wọn
danu nigba ti ajo eleto idibo nigba naa ti kọkọ kede pe Funṣọ
William’s lo wọle
ṣugbọn nigba tilẹ ọjọ keji yoo fi mọ, wọn ti ṣojooro pe awọn lawọn wọle pada ẹlẹẹkeji.
O ni iyẹn tun lọ, lọdun 2007, tawọn araalu tun
mura silẹ
lati jẹ
ki Funṣọ
William’s wọle,
ṣe
lawọn
ẹni
ibi da
ẹmi
ẹ
legbodo, awọn
eeyan wa sọ
nigba naa pe awọn
ko mọ ẹni
to pa ọkunrin
naa ṣugbọn idahun temi
maa n fun wọn
ni pe awọn
to jere nipa iku ẹ
ni ki wọn
roo si.
O tun ṣalaye pe ipo
to yẹ
ki ipinlẹ
Eko wa kọ
lo wa a,
bi a ba ni ka a
sọ
nipa eto ọrọ aje atawọn idagbasoke, ṣugbọn o ni, nigba
to jẹ
pe awẹn
ẹbi
kan ni wọn
fẹẹ
maa paṣẹ,
ki aṣẹ
gbogbo ipinlẹ
Eko wa lọwọ wọn, o ni asiko ti
wa to tawọn
araalu ṣetan
lati fi ibo le wọn
danu. Ko si nnkan to n jẹ babakresi tabi baba sọ pe mọ.
Oludije naa tun ṣalaye siwaju pe
ẹgbẹ ADP ipinlẹ naa ti mura silẹ fun yiyan awọn oludije ti wọn yoo dije labẹ ẹgbẹ naa, o ni
gbogbo awọn
ọmọ ẹgbẹ ni wọn yoo ṣe ojuṣe wọn lati dibo fẹni to ba wuu, o
ni ẹgbẹ naa ti kọja, ẹni ti yoo maa
fowo ra ibo lọwọ awọn ọmọ ẹgbẹ.
O ni bi awọn ọmọ ipinlẹ Eko ba le fun ẹgbẹ oṣelu ADP laaye lati
jawe olubori ninu ibo gomina to n bọ naa, gbogbo nnkan
tawọn
fẹẹ ṣe
lati le jẹ
ki ipinlẹ ọhun ba tawọn agbaye yooku
mu, ko gba wọn
ju ọdun
kan lọ,
nitori awọn
ti ko to Eko
lagbaye, o
nibi ti wọ de
bayii.
Ati pe awọn iṣoro ti ko yẹ ko maa dojukọ wa bii omi,
ina, atunṣe
oju popo lawọn
araalu n dojukọ
pẹlu
bi owo ṣe
n wọle,
bakan naa,
lo ni eto ibanisọrọ wa
gan-an ko ja geere to,
ti ko si yẹ
ko ri bẹẹ, o wa beere pe iru ijọba wo wa ni a n
lo nipinlẹ
Eko.
Ọpọ awọn to n ṣakoso ipinlẹ Eko lo sọ pe o yẹ ki wọn wa nibi ti wọn ti n tọju ṣugbọn ni bayii, o ni
opin ti de ba iru awọn
aṣaaju
bẹẹ
nitori wọn
ti sun awọn
araalu kan ogiri, ohun ti wọn wa ni ijọba tuntun ti yoo
le ṣe
gbogbo nnkan ti wọn
ba n fẹ,
ti ko ni si pe wọn
fi ara ni araalu.
O wa sọ pẹlu idaniloju pe
ireti ṣi
wa fun ẹgbẹ oṣelu ADP lati gba
akoso ipinlẹ
Eko, nitori ariwo ayipada rere ti ki i ṣe ti APC
lawọn
araalu pariwo bayii.