...O ni ko ṣẹlẹ ri latigba to ti wọnu oṣelu
Ọjọ manigbagbe lọjọ oni- in jẹ ninu itan Atiku Abubakar, to ti figba kan jẹ igbakeji aarẹ orileede yii to tun fẹẹ dije fun ipo aarẹlabẹ ẹgbẹ oṣelu PDP ninu ibo to n bọ lọdun 2019,
Idi abajọ ni pe awọn alatilẹyin ẹ ni wọn ko ara wọn jọ, ti wọn da owo ti wọn fi gba afọọmu pe mo nifẹẹ lati dije fun ipo aarẹ funọkunrin naa.
Ohun to si jẹ ko ri bẹẹ ni pe lati igba tiọkunrin naa ti wọnu oṣelu, to ti n jade lati dije fun ipo, igba akọkọ ree tawọn kan yoo ko ara wọn jọ ti wọn yoo gba fọọmu funọmọ Adamawa naa. Nibi tọrọ naa dun unde, ko mọ igba ti omi n bọ loju ẹ to sọ pe oun ko nireti pe awọn kan le ṣe iru nnkan bẹẹ foun.
Nibi ayẹyẹ naa to waye ni ọfiisi ẹgbẹ naa to wa ni Wuse,niluu Abuja lawọn alatilẹyin ẹ yii ti sọ pe awọn gbe igbesẹ naa lati jẹ iyalẹnu ti ko lero lọkan fun un ati pe awọn nigbagbọ pe Atiku lawọn iriri to fi le gbe orileede yii de ebute rere.
Aṣaaju awọn ikọ awọn obinrin, Ọmọọba Adekẹmi- Adesanya Ẹboda to jẹ aarẹ ẹgbẹfawọn obinrin to n ṣatilẹyin fun Atiku iyẹn WAYS, sọ pe awọn obinrin ti n foju sọna fun Atiku lati gba awọn ọmọ orileede yii silẹlọwọ ijọba ti ko nitumọ tẹgbẹ APC n dari.
O loun gbẹnu sọ fun gbogbo awọn obinrin ti ilọsiwaju orileede yii jẹ pataki fun un pe ki Atiku ma ṣe boju wẹyin lati dije awọn wa pẹlu ẹ, gbogbo nnkan ti yoo ba si na awọn lawọn yoo ṣe lati ri i pe ọkunrin naa dori ipo naa.
Ọgbẹni Edwin Adai toun naa jẹ aṣaaju lara awọn alatilẹyin lo gbe fọọmu naa le Atiku lọwọ lorukọ gbogbo wọn.
Nigba to n sọrọ, Atiku ti ko mọgba ti omi bọloju ẹ dupẹ lọwọ awọn eeyan naa fun ohun ijọniloju ti wọn ṣe e foun yii.O ni igba akọkọree ti iru nnkan bẹẹ yoo ṣẹlẹ latigba to ti wọnu oṣelu. O ni pelu nnkan ti wọn ṣe yii, o ti fi han pe ajọṣepọ to danmọran ti wa ati pe awọn yoo jọ ṣiṣẹ naa pọ ni.Pẹlu idaniloju pe awọn yoo jọ bori papọ ni.
No comments:
Post a Comment