Alaga ẹgbẹ oṣelu ADP nipinlẹ Eko, Adewale Abọlaji, ti muu da gbogbo awọn eeyan ipinlẹ naa loju pe ẹgbẹ naa ti ṣetan lati gbakoso lọwọ ẹgbẹ oṣelu APC ninu ibo gomina to n bọ lọdun 2019. O sọ idaniloju yii lakooko to n ba awọn oniroyin sọrọ.
O sọ pe gbogbo ọna lawọn yoo gba lati ri i pe ẹgbẹ naa mu awọn araalu kuro loko amunisin tẹgbẹ APC ko wọn si i, ati pe awọn ti gbaradi fun idibo naa. O ni titi di akoko toun sọrọ yii lawọn eeyan to fi mọ awọn ọdọ atawọn obinrin fi n darapọ mọ ADP.
Adewale tun ṣalaye siwaju pe ẹgbẹ oṣelu to wa lode yii ti da awọn araalu, wọn si tun n da wọn lọwọ bayii, Ọlọrun nikan lo ni o le gba wọn loko ẹru awọn ijoba naa, idi niyi tawọn araalu fi pinnu pe ẹgbẹ oṣelu ADP nikan lọna abayọ to le gba awọn kalẹ.
Bakan naa lo sọ pe ẹgbẹ ADP ni awọn eto to lagbara fawọn ọdọ, nitori pe awọn gan-an ni wọn n dibo ju, ohun to si ṣẹlẹ ni pe a-lo- pa-ti lawọn oloṣelu maa n fi wọn ṣe, eyi ti tawọn ko ri bẹẹ, o ni aye wa fun wọn lati jade ki wọn dije fawọn ipo to wa nilẹ, o si da oun loju pe wọn yoo wọle.
O tun fikun ọrọ ẹ pe ko si ọdọ kan to wa ninu ẹgbẹ naa ti yoo kabamo pe oun darapọ mọ awọn, awọn ọdọ naa si ti bẹrẹ iṣẹ lati ri i pe ninu ibo to n bọ naa, wọn ko fawọn sẹyin, bẹẹ lo tun ni awọn obinrin naa ko gbẹyin ninu awọn eto wọn ninu ẹgbẹ naa.
Lori kaadi alalopẹ iyẹn PCV, Alaga naa sọ pe o fẹẹ jẹ pe ẹgbẹ oṣelu ADP nikan lo n polongo ẹ fawọn araalu ju lati lọọ gba kaadi naa ki anfaani le wa fun wọn lati kopa ninu ibo to n bọ yii. O wa pari ọrọ ẹ pe pẹlu bi nnkan ṣe n lọọ yii, ki ẹgbẹ oṣelu APC di ẹru wọn silẹ, nitori o da oun loju pe awọn ni yoo gbakoso Alausa lagbara Ọlọrun.
No comments:
Post a Comment