Alaga fẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Eko, Ọnarebu Moshood Salvador, ti ke si alaga fẹgbẹ oṣelu naa lapapọ niluu Abuja lati le Oloye Bọde George atawọn eeyan mẹwaa mi-in kuro ninu ẹgbẹ naa bi wọn ba fẹẹ jẹ koun ṣiṣẹ gẹgẹ bi ipo ti wọn yan oun si.
O sọrọ yii l’Ọjọbọ, Tọsidee, nigba to n bawọn ọmọẹgbẹ naa ṣe ipade pọ, eyi to waye laduugbo Maryland niluu Eko. O sọ pe ọkunrin naa to n pe ara ẹ ni olori ẹgbẹ naa lo n da wahala silẹ ninuẹgbẹ oṣelu naa, to si n fẹẹ kawọn eeyan wa maa gbaṣẹ lẹnu rẹ, ki wọn to ṣe ohunkohun ati pe inu ile ẹ lo ti fẹẹ jẹ ki wọn maa ṣe ohun gbogbo to ba tọ si ẹgbẹ naa.
Bakan naa lo sọ pe bi ki i ba ṣe ọpẹlọpẹ Ọlọrun, o ku diẹ ki Bọde George ran oun lẹwọn lori iṣẹlẹ to waye ninu oṣu keje, nibi ti wọn ti pa alaga ijọba ibilẹ PDP ni Apapa iyẹn Ọgbẹni Adeniyi Abọriṣade. Ọkunrin naa ko fi ọrọ sabẹ ahọn sọnigba to sọ gbogbo ipa ti Bọde George ti ko lati mu ifasẹyin ba ẹgbẹ naa lati ibẹrẹ pẹpẹ.
Gẹgẹ bi alaye alaga naa, o ni Bọde atawọn eeyan ẹ gbimọ pọ lati sọ nnkan ti ko ṣẹlẹ nipa wahala to waye ni Eti Ọsa naa lati fi ran oun lẹwọn ṣugbon oun dupẹ lọwọ awọn ọlọpaa atawọn agbofinro pe wọn ṣisẹ wọn gẹgẹ bi iṣẹ, wọn si ri i daju pe oun ko mọ nnkan kan nipa wahala naa.
O ṣalaye siwaju pe ’Latigba ta a ti ṣe ipade ẹgbẹ oṣelu wa ni Ọrẹgun nibi tawọn ọmọ ẹgbẹ ti pọ to ẹgbẹrun lọna ogoji, la a ti ri i pe ibi ta a ti ṣe gan-an ko le gba wa mọ, koda bi a ba ni ka a ṣe ni ọfiisi wa, ko le gba ero, idi niyii ta a fi pinnu lati maa ṣe ipade naa kaakiri awọn ijọba ibilẹ wa lati fi maa bawọn ọmọ ẹgbẹ sọrọ.
‘A ti ṣe iru ipade bayii ni Ẹpẹ, Ọjọ, Amuwo Ọdọfin, Oṣodi- Isọlọ atawọn ibo mi-in ti wọn fi jẹ ijọba ibilẹ mẹtala ti ko si wahala kankan nibẹ, iru ẹ naa la lọọ ṣe ni Eti-Ọsa lọjọ naa. Ka to bẹrẹ lọjọ naa ni alaga PDP ijọba ibilẹ ibẹ to jẹ eeyan ti Bọde George ti kọkọ da awọn aga ijokoo ru, ti mo ni ki wọn fi silẹ’
O tun sọ ninu ọrọ ẹ pe ṣe lo n sare wọnu mọto ko to di pe wọn bẹrẹ rogbodiyan, lẹyin-o-rẹyin loun gbọ pe wọn ti pa Aboriṣade ṣugbon nigba to ni awọn ti Bọde George maa hun irọ jọ, wọn sọ pe oun mọ nipa bi wọn ṣe pa ọkunrin naa.
Ọpẹlọpẹ awọn ayaworan ti wọn wa nibẹ, bawọnọlọpaa ṣe ni koun yọju pẹlu awọn ẹlẹri oun, toun de Panti, ṣe ni wọn da gbogbo wọn satimọle. Amọ oun dupẹ pe awọn ọlọpaa atawọn agbofinro ri okodoro ọrọ.
Salvador ni gbogbo erongba Bọde Geroge ni pe gbogbo nnkan ti ẹgbẹ naa ba fẹẹ ṣe, wọn gbọdọwa ṣe nile ẹ, to fi mọ ipade awọn oloye ẹgbẹṣugbọn tawọn ko gba fun un, o nile oun gan-an ju ile ẹ to n pọn le naa lọ.
Bakan naa lo sọ pe aimọye owo tara oun loun ti na si apo ẹgbẹ naa, nitori ki ilọsiwaju le de baẹgbẹ naa, ko wa yẹ ki Bọde George ti ko lẹnu nibẹni wọọdu ẹ maa da gbogbo eto awọn ru, o wa ke si awọn oloye ẹgbẹ niluu Abuja lati le ọkunrin naa kuro ninu ẹgbẹ nitori agba ọbayejẹ ati agbẹyinbẹbọ jẹ ni.
No comments:
Post a Comment