WAHALA DE: NITORI FAYOSE, NGIGE FEE DA IPOLONGO EGBE OSELU APC RU L'EKITI - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, July 11, 2018

WAHALA DE: NITORI FAYOSE, NGIGE FEE DA IPOLONGO EGBE OSELU APC RU L'EKITI

Oro buruku toun terin loro ri niluu Ado-Ekiti lojo Tusde to koja yi nibi ipolongo idibo gomina ipinle Ekiti to fe e waye lojo Satide to m bo yi, nibi tawon agba egbe oselu APC, to fi mo Aare Muhammadu Buhari ti peju pese sibe.


Gege bi a se gbo, Minisita foro awon osise, Oloye Chris Ngige ni won loo fe e da ipade naa ru patapata, sugbon ti won lawon eso alaabo ni won pana wahala to fe e be sile naa.

AWIKONKO gbo pe oro Gomina ipinle Ekiti, Ayodele Fayose ti Ngige mu senu pe oun ni ki won dibo fun lojo Abameta Satide to m bo yi, dipo Fayemi ti won wa a gbe laruge lo da wahala sile, tawon omo egbe oselu PDP si n so pe ko sibi ti APC n lo nipinle naa.


Ninu oro Minisita foro awon osise naa, o so pe "O maa sele lojo Satide, eyin ti e fe ki Satide see se, e na owo yin soke pelu kaadi idibo alalope, PVC yin pelu awon nkan to ku. Aare wa, eyin oloye egbe oselu wa, awon eeyan wa ti gbaradi, won ti gbaradi ati pe gongo maa so lojo Satide, paapaa fawon to wa lati Southwest pelu asise ti won se lodun 2014, ki won si ma baa se iru asise naa pada mo. Ti eeyan ba fe iyawo meji, o maa mo eyi to dara ninu won.

"Fayose ni iyawo to dara, o mo ounje se, o mo bi won se n fun oko ni ounje to dara. Kii fun un ni wahala, nitori naa le se gbodo da Fayose pada lojo Satide."

Ibi ti Ngige soro de re e ti Arabinrin ti won jo duro fi loo fowo too pe kii se Fayose lo ye ko maa daruko, Fayemi ni, nitori pe Fayemi lomo egbe awon tawon wa a gbe laruge.


Bo tile je pe AWIKONKO ko tii le fidi oro naa mule, ohun ta a gbo ni pe nigba ti won beere owo lowo Dokita Ngige pe ki lo de to se iru asise nla beeyen, ohun to so fun won ni pe Olorun lo gba enu oun soro.

Won ni Ngige loun mo pe asise loun n se, sugbon oun ko mo boun yoo se ko ara oun nijanu lasiko toun n soro nitori pe emi Olorun lo n gba enu oun soro. Bee ni won loo so pe oun ti salaye fun Aare Buhari pe ko je kawon gbagbe ipinle Ekiti.

Ohun topo awon omo Naijiria to wo fonran naa to n kaakiri n so ni pe aye lo tele Ngige de ibi ipolongo naa, ati pe asasi Fayose lo mu won, ti won fi n so isokuso.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI