Se ni idunnu subu lu ayo osise meje ninu awon omo egbe fijilante ti Alimodu Sokoto nipinle Ogun lonii ojo Tosde nigba ti oga won nile Yoruba (Assistant Commander General), Enitan Emmanuel fun won ni igbega kuro ni ipo ti won wa tele.
Olu-ileese won to wa ni Asero Housing Estate, Abeokuta ni won ti se eto idanilola naa lasiko ipade olosu meta-meta ti won maa n se pelu awon omo egbe naa lati mo ibi ti ise won de duro, ati awon iroyin to n lo latodo awon alase woin niluu Abuja.
Nibi ipade naa ni won tun ti se idanilekoo fawon olori awon osise naa kaakiri ipinle Ogun ti won peju pese sibe.
Awon meje naa ni: Role S. Adewale to je Group Commander (Admin Southwest II Zonal) ati Oluwole John to je Deputy Commander (Admin Southwest II Zonal).
Awon to ku ni Adeniji Sunday, Adelaja Yaya, Bello Hammed, Eleshin Ganiyu ati Conquerors Esther ti won je igbakeji Komanda (Asst. Commander, Finance Zonal).
Nigba to n soro lasiko idanilekoo naa, igbakeji oga agba patapata naa, Ogbeni Enitan Emmanuel so pe o se pataki fawon osise naa lati tun imura won se daadaa, nitori pe imura gan an lo maa so iru eeyan ti won je, ati pe bi won ba se mura naa lawon eeyan yoo se ri won.
Bee lo gbawon nimonran pe ki won sunmo awon araalu, paapaa awon agbegbe ti won ti n sise. O ni won gbodo rii pe ibasepo to dan monran wa laarin awon atawon agbaagba, paapaa awon baale adugbo ti won ti n sise ki won le je kawon eeyan ti won n daabo bo le maa foju gidi wo won.
Enitan nigba to n soro lori bi VGN se pin si meji, o so pe ko si nnkan to n je pe awon pin si meji, bi ko se pe awon kan ni won fe e ba VGN je, tawon si ti n gbe igbese lori bi isokan yoo se pada sinu egbe naa, nitori pe alaafia ati isokan lo je won logun.
No comments:
Post a Comment