TA NI FULANI DARAN-DARAN?? - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, July 6, 2018

TA NI FULANI DARAN-DARAN??

Baa wi, a maa ku; ba o si so, dandan ni iku. Sugbon ki ba dara fun akoni omo Oduduwa ko so otito kosi duro si ori ododo nitori pe igbagbo wan ni pe baba nla wa Oduduwa gan an feran otito nigba aye re pelu.


Olorun Oba gan an fi idi e mule ninu awon iwe mimo mejeji pe otito dara.

Kinni ka ti pe gbogbo rogbodiyan to n sele kaakiri orileede yi, iku lonii, oro lola, ijamba ina, walaha awon Fulani adaranje ati bee bee lo to n sele kaakiri orileede Niajiria jo pe o ni owo kan oselu ninu tabi ki n so pe o ni owo kan awon olu’baluje lowo. A bi kinni ka ti pe ti ipaniyan nipakupa awon Fulani darandaran wonyii?

Sugbon saa, a ko gbodo gbagbe pe ijoba nikan ko le da oran yii yanju bi ko se pe ka fi owo sowopo lori rogbodiyan yii, ka si gbaruku ti ijoba to wa lode.

Lakoko naa, e je ka bere lati odo awon Fulani adaranje, lati ojo to ti pe ni Fulani ti n da eran won je oko kaakiri, sugbon ibeere mi ni pe 'ta gan ni Fulani darandaran?', Fulani darandaran ni awon eya Fulani sugbon ti ko ni ile to ka-n-ka (Nomads), sugbon ti a tun le daa pe ni alarinka, apa oke oya ni won po ju si, won po niye nitori pe won je iran kan ti  o ma n bi omo to po, fun idi eyi ko fee si apakan tabi ibile kan ti e ko ti ni ri Fulani.

Won ni ti ko ba ni idi ese ki dede se. Kinni idi pataki ti awon Fulani se wa di eni to n fa wahala. Gege bi mo se so siwaj, Fulani adaranje won koni ile-to kan ni pato, fun idi eyii awon ole aji eran saba ma n yo won lenu, eyi ti opo si ma n padanu emi ati dukia re si owo awon ole won yii (Cattle Rustler), fun idi eyii awon naa gbimo po lati ma gbe awon ohun ija oloro bi ibon, obe, ati ofa dani nigbakugba ti won ba n da eran won kaakiri.

Eleyii lo si ma n fun won ni igboya lopolopo igba lati tase ageere si awon agbe to da oko, beeni opolopo iwa ibaje miiran ni a gbo pe won ti hu nitori igboya ati igbagbo ti won ni lori awon ohun ija oloro ti won n gbe dani. Lati ojo to ti pe ni a ti mo Fulani adaranje mo wahala sugbon iwa ibaje won tun wa peleke sii, paapaa nigba tijoba Buhari de ari aleefa.

Gege bi onka ti Institute for Economics and Peace fi sita lai pe yii, won ni lodun 2014, egberun kan, igba ati mokan dilogbon (1229) lawon eeyan ti won padanu emi won. Ninu osu karun un odun 2015, ogorun kan le die (100+) lawon agbe ati awon ibatan won ti won padanu emi won si owo awon Fulani adaranje ni awon agbegbe kan bii Ukura, Ler, Gafa ati Tse-Gusal to wa nipinle Benue.

Nigba to di osu kefa odun 2015, awon Fulani Adaranje wonyii tun se ikolusi si agbegbe Adeke nilu Makurdi ti opolopo emi ati dukia si ba isele naa lo. Gbogbo wa la gbo ohun to sele nipinle Benue lai pe yii, ni bi ti opolopo emi ati dukia ti sofo danu.

Eje ka bi ara wa ni ibeere yii pe, 'Nje awon Boko Haram ko ti dapo mo on awon Fulani adaranje bayi? Abi kinni ero ti yin lori oro Ajoro yii, Awon kan ti le so pe awon ajoji lati orileede Cameroon ni won wa nidi isele isekupani to n waye wonyii. Sugbon ti e ko ba gbagbe pe leyin ikolu awon Fulani adaranje eyi to wa ye ninu osu keji odun yii, awon egbe adaranje gba wipe awon omo egbe awon ni won se ikolu to waye naa.

Bee si tun ni abaranti Ikolu eyi to waye ni Ekiti nibi ti Gomina Ayodele Fayode ti pase fun awon figilante ati awon agbe pe ki won je oju-lalakan-fi-n-sori. A tie tun gbo pe egbe awon Gan Allah Fulani so pe isekupani to waye yii, lati owo awon Fulani adaranje si odo awon agatu pe esan ni awon fi gba latari awon eeyan won ti won lawon agatu pa.

Nje ogun ko lo n rugbo bo bayii. Nje to ba sele tan agbara ijoba yii ka a? E ma je ka gbagbe ohun to sele ni orileede Olominiran Congo lojosi, nipa awon emi to sofo danu.

Eje ki n kadi oro mi pelu ibeere pe 'nje apa ijoba ka wahala awon Fulani adaranje yii, a bi awon Fulani adaranje gaa ju ofin orileede Niajiria lo ni? Mo mo pe eyin oloye n ka iwe iroyin AWIKONKO. E le fi ero ti yin naa ranse si wa.

Idibo miiran lo tun n bo yii o, beeni opolopo oludije lo ti n fi ife won han sipo kan tabi omiiran. Eyin onkawe wa, e ranti pe emi Tayo Adio ko bu dudu, beeni mi soro abuku si pupa, sugbon ohun ti mo n so ni pe, e je ka ranti pe ohun ti a ba se lonii yoo pada di itan agbofikogbon ni ola.

E je ka ronu daadaa ka too dibo fun awon oludije, ka si parapo forikori won eyii ti a ba rii pe iwa dara ninu won, ka too teka fun un, nitori pe taa ba ni ko kan wa lonii, e ranti pe o seese ko kan eni ti yoo kan wa kan to ba di lola. Awon agba bo, won ni 'o n bo, o n bo, awon la n de de', sugbon ni seyin gbogbo ara ni an muto.

E pade mi lose to n bo ni abala yii, 

TAYO ADIO
+234(0)810-5088-418

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI