Ojo Tosde to koja yi ni oga agba ajo naa, Komanda Philip Ayodele soro naa jade sita niluu Abeokuta nibi ipade gbogboogbo ti eka won to n ri soro alaafia laarin ilu (Peace and Conflict Management Department) maa n se leemeji lodun.
Ayodele so pe o se pataki lati ni awon ofiisi ti won ti ma maa se ipade lati fi yanju aawo, wahala tabi ogun laarin awon eeyan, ileese ati ilu, nitori pe dandan ni alaafia je, paapaa bo tun se je pe ise tijoba gbe le won lowo ni lati dekun wahala laarin ilu.
Oga agba naa je ko di mi mo eka to n ri si oro alaafia nileese won yi lo maa n yanju orisirisi oro ija tabi wahala to ba n sele laarin awon egbe kan tabi eeyan lai si pe won lo sile ejo, iyen kootu.
Bakan naa lo tun tenumo on pe ko din ni oodunrun (306) ni awon wahala ni won fi to awon leti, to si je pe 130 ninu e lawon ti wa iyanju si patapata, nigba tawon si n sise lori 263 to ku, iyen laarin osu mefa akoko ninu odun yii.
O ni ninu awon wahala naa la ti ri ejo merindiaadota (46) to nii se pelu oro owo, ti marundinlaadota (45) ninu ejo naa je loro oro ile (land dispute), nigba ti mokanlelogota (61) ninu e je lori oro igbeyawo.
Bee lo tun so pe awon ti n sise takuntakun lati towo bowe adehun pelu awon ileese to dangajia lati jo sise papo da awon ibi ti won ma maa yanju aawo kaakiri ipinle Ogun, ti yoo si je irorun fawon araalu lati mo ibi ti won yoo maa gbe ejo lo dipo kootu.
Ninu oro oludamoran fawon ileese adani (Advisor, Private Sector Department, GIZ) to wa niluu Abuja, Ogbeni Akinropo Omoware so pe ileese won ti n sise lori bi ise ati okoowo yoo se maa lo daadaa nipinle naa.
Omoware so pe ileese GIZ je ileese to n ri si bi won se n pari aawo laarin awon ileese olokoowo, tawon si ti setan lati gbaruku ti ajo Sifu Difensi pelu ipinu won lati maa yanju aawo ati wahala laarin ilu.
No comments:
Post a Comment