Otunba Rotimi Paseda ti ke si ijoba apapo lati bere ise kiakia lori ona reluwe eyi ti yoo dena awon ijamba to maa n waye lawon oju ona gbogbo.
Paseda soro yii ninu atejade ti Ogbeni Micheal- Azeez Ogunsiji to je oludamoran e lori eto iroyin fi sita lati ba awon eeyan ipinle Eko kedun tanka to deede lana lagbegbe Otedola loju Eko si Ibadan nibi tawon eeyan mejila ti gbemi mi ti opo moto sii jona raurau. Eyi to waye l’Ojobo, Tosde, ose to koja.
Paseda so pe isele naa je eyi to ba ni lokan je, to si mu omi loju, sugbon o lo akoko naa lati kesi ijoba apapo pe ki won tete pari ise lori awon ona reluwe ti won ti bere.
Oludije sipo gomina labe egbe oselu UPN nipinle Ogun tun ro won lati rii pe won nawo lori ona reluwe yii, eyi yoo le dina awon ijanba ojo iwaju.
Bakan naa lo tun rawo ebe si isakoso Aare Muhammadu Buhari lati gbe igbese to lagbara lori oro yii, eyi to ni yoo tun daboobo emi atawon dukia loju popo.
O wa ranse ibanikedun sawon ebi tisele naa sele si pe ki Olorun ko tu won ninu. Bee lo tun ro ajo eso oju popo iyen FRSC lati maa sa ipa won looorekoore lati le je ki adinku ba ijanba loju popo wa.
No comments:
Post a Comment