OWO FIJILANTE TE ODARAN MEJI TI WON FEE JI IRINSE IPINLE OGUN GBE - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, July 28, 2018

OWO FIJILANTE TE ODARAN MEJI TI WON FEE JI IRINSE IPINLE OGUN GBE

Kani kii se pe awon Fijilante tijoba apapo, iyen Vigilante Group of Nigeria, VGN ti won wa nijoba ibile Yewa North ko sun asunpara ni, o see se kawon odaran meji kan ti won so pe won ko nise meji ju ki won maa jale lo, ti ji awon irinse tijoba ipinle Ogun fe e lo lati fi ko papako ofurufu ti Cargo gbe lo.


Gege bi AWIKONKO se gbo, ni nnkan bi aago mewaa aabo ojo Fraide to koja yi la gbo pe awon odaran naa lo sagbegbe Ogusi to wa nijoba ibile Ewekoro, nibi ti ijoba ipinle Ogun n ko papako ofurufu ti Cargo naa si lati ji awon irinse ti won n lo nibe gbe.

A gbo pe tirela nla kan lawon odaran meta naa ti won pe oruko won ni Ogundele Johnson, Densi ati eni kan ta a ko tii mo oruko titi dasiko ta a sakojopo iroyin yi tan, ti won loun na papa bora lasiko tasiri won tu sawon eso VGN naa lowo.


Nigba to n b'AWIKONKO soro, igbakeji oga agba egbe VGN naa lori oro ise (Deputy State Operation), Ogbeni Osuala Jimoh so pe okan lara awon omose oun lo pe oun lori aago pe oun kofiri awon odaran naa lasiko toun n sise koja lagbegbe naa.

Osuala so pe biroyin naa se te oun lowo loun ti ranse pe awon osise min in lati loo ba won nitori pe ibi toun wa jinna sibe, lesekese lo ni won ti gbera loo ba won.

AWIKONKO gbo pe bawon odaran naa se rii pe asiri won ti tu nibi ti won ti n ko awon irin (iron rods) naa sinu tirela ti won gbe wa, ni won ti doju ibon ko won lati yin in fun won, sugbon ta a gbo pe okan lara awon osise VGN naa mu won lati eyin.

Nibe la gbo pe won ti wo iya ija repete, sugbon towo pada te won, ta a si gbo pe okan lara awon odaran naa salo pelu okada to gbe wa.


Adeniyi Kazeem ati Salimon Ezekiel to je osise VGN naa la gbo pe won rowo to awon odaran naa, lesekese la gbo pe won ti loo fa won le awon olopaa Itori lori lati tesiwaju ninu iwadii, ki won si le fiya to to je won labe ofin.

Nigba to n b'AWIKONKO soro lori isele naa, oga agba egbe naa, Komanda Olanrewaju Nureni Adedoyin bu enu ate lu iwa tawon odaran naa hu, to si so pe ko ye ko je irinse tijoba fe e fi tun ipinle naa se lo ye ki won gbero lati loo ji gbe.

O seleri eto aabo to pe ye fawon araalu pe egbe awon ko nii la oju sile gba awon laaye nipinle Ogun, lasiko toun ba si n je oga agba egbe naa, nitori pe aabo emi ati dukia awon araalu lo je oun logun pupo, to.si je pe ise tawon gba niyen.

Bakan naa lo tenumo on pe VGN ko nii lati maa fowosowopo pelu awon ileese eleto aabo to ku bii ileese olopaa, ti won je iya awon.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI