Lati le din ise ati osi ku, paapaa airise se
awon odo lorileede Naijiria, olori ati oludasile soosi Treasure House of God to
wa ladugbo Agbeloba, Abeokuta, Pasito Adeseye Senfuye ti bere irolagbara fawon
odo, eyi ti yoo mu won kuro ninu ise ati osi.
Gege bi atejade ti alakoso iroyin fun soosi
naa, Ogbeni Adeniyi Adeloye se fi to AWIKONKO leti lojo Sande to koja yi, a gbo
pe ara oto ni irolagbara naa je, ati pe lati mu erin pa ereke ogunlogo awon odo
ni eto naa wa fun, paapaa ki edinku de ba isoro airise se.
Eto iforukosile naa ta gbo pe gbogbo odo
kaakiri orileede Naijiria ni won i anfaani lati loo forukosile, nitori pe ojo
Satide to koja yi, iyen ogbon ojo osu kefa si ojo kokanlelogun osu yi ni eto
iforukosile yoo fi waye ninu ogba soosi naa to wa ni 177, Quarry Road,
Agbeloba, Abeokuta.
Nigba to n gba enu Pasito Senfuye soro,
Ogbeni Adeniyi so pe kii se pe Pasito naa dee de gbe eto yi kale lati se
iranlowo fawon odo, sugbon lati le mu edinku ba airise se awon odo, ki opo odo
to wa ni orileede yi le ri nnkan maa fi pa owo da lo mu ipinu yi wa.
O ni ona kankan soso lati le mu idagbasoke ba
orileede yi ni lati ro awon odo lagbara, nitori pe ijoba apapo orileede yi naa
n gbiyanju lati je kawon odo ri ise se.
Bakan naa lo tun je ko di mi mo looto lawon
odo je ojo iwaju orileede yi, ti won si tun se pataki daadaa, nitori naa lo se
je pe ojo iwaju won je oun logun pupo, toun si gbodo tete wa ona abayo si isoro
won.
Bee lo tun so pe won yoo ko awon odo nise
owo, bee naa ni won yoo tun fun won lowo ti won yoo fi bere ise won.
No comments:
Post a Comment