Oloye Mulikat Ejide ti won sese yan gege bii Otun Aluwo ipinle Ogun ti ro awon omo orileede Naijiria, paapaa awon omo ile Yoruba pe ki won ma se pa asa ati ise awon baba nla won ti, nitori pe asa ko di esin ti won n sin lowo.
Ojo Abameta Satide to koja yi ni Oloye Mulikat Ejide, eni to tun je Iya Orisa ilu Egba soro naa jade ninu gbagede ayeye ti Alake ile Egba, to wa ladugbo Ake, Abeokuta lasiko iwuye Otun Aluwo ipinle Ogun ti won sese fun un.
Arabinrin Ejide je ko di mi mo pe o di dandan fawon omo Yoruba lati maa gbe asa, ise ati isese won laruge nitori pe ko si asa to dara to asa ile Yoruba lagbaye, tawon oyinbo funra won naa si n ko nipa e lojoojumo.
Ejide ni bo tile je pe oye idile ni oye tuntun ti won sese gbe foun naa, iyen Otun Aluwo ipinle Ogun to tunmo si Alabojuto gbogbo orisa nipinle Ogun, sibe idunnu nla lo je foun, toun si gbodo fi idunnu ati ayo han sii.
"O di dandan ka maa gbe asa ile wa laruge ni gbogbo igba, beeyan ko ba gbe asa, paapaa asa ile Yoruba laruge, bi eni to so wura nu ni. Oye kii paayan, ole lo n paayan, bi won ba fi eeyan je oye kan, dandan ni ko lo ipo naa daadaa lati fi tun ilu to ba fe e baje se. Oruko rere si san ju wura ati fadaka lo.
"Orisa Igunnuko je orisa to dara, orisa olomo wewe ni, kii je epo, Imale tun ni, nitori naa lo se je pe awon Imale lo po ju to.n se e, iyen awon to n je oruko Imale. Igunnu kii se orisa to n gba idoti Mora, orisa to feran imototo ni. Igunnuko kii puro, beeyan ba si fi otito inu sin in, o di dandan ko ri igbala lodo e. Otito inu ti mo fi n sin in ni mo n je lonii, ti mi o si kabamo."
Okan lara awon alejo pataki ayeye naa, Alaaji D.S Adegbenro so pe idunnu nla lo je foun lati wa nibi ayeye naa, nitori pe oun ko tii bawon kopa nibi iru ayeye isese bayii ri. O ni bii igba toun je tete lo ri pelu awon nnkan iwuri toun foju ri.
Alaaji Adegbenro tenumo on pe looto lawon eeyan, paapaa ijoba ko mu oro asa lokunkundun tele, sugbon pelu awon nnkan to n jade lati eka asa, a gbodo maa ko eko lati maa gbe asa ile wa laruge, ko ma baa parun.
O so pe o pan dandan lati mu ede Yoruba lokunkundun lawon ile eko kaakiri nitori pe ohun ta a jogun ba ni, bi ijoba ko ba si tete gba ruku tii, iparun ni yoo je fun asa wa.