NITORI OMIYALE, OSINBAJO SABEWO SILUU ABEOKUTA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, July 18, 2018

NITORI OMIYALE, OSINBAJO SABEWO SILUU ABEOKUTA

Igbakeji Aare orileede Naijiria, Ojogbon Yemi Osinbajo ti sabewo siluu Abeokuta latari ojo oni wakati meji aabo to ro lojo Fraide ose to koja yi, to si fa omiyale, agbara ya soobu.


Ni nnkan bi aago merin aabo irole onii, Wesde ni Ojogbon Yemi Osinbajo bale sinu gbagede tawon ologun to wa ni Oke-Mosan, Abeokuta nibi ti Gomina Ibikunle Amosun atawon amugbalegbe e, to fi mo awon oniroyin ti duro de e.


Be o ba gbagbe, omiyale naa lo gbe opo awon eeyan lo, ti won ko si tii ri pupo ninu awon ti agbara gbe lo, ti opo dukia si tun sofo danu.


Gege bi a se gbo, ko pe ti igbakeji Aare naa bo sile ninu oko baalu ayarabiasa (Helicopter) ni won ti gbera lo sawon agbegbe ti agbara naa ti wo ile, to gbe awon eeyan lo, to si tun ba dukia je.


Ko si nnkan meji to gbe igbakeji Aare, Ojogbon Osinbajo wa siluu Abeokuta, bi ko se lati mo awon iranlowo tijoba apapo fe e se fawon to se agbako isele naa, ati lati mo awon igbese lati dekun omiyale bi iru ojo bee ba tun ro.


Lara awon agbegbe ti won lo naa ni: Iyana-Mosuari, Ago-Ijesha, Itoku, Lafenwa, Kuto, Isale-Igbein, Amolaso, Olomore atawon min in.











No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI