Gege bi AWIKONKO se gbo, ilu Bogitaa ni Kiisi loro naa ti sele, nigba ti won so pe Zipporah fesun kan iyawo egbon e, Rose Kemunto pe o fe e gba oko moun lowo.
Ohun ta a gbo ni pe Rose lo ranse pe oko afesona e, Joseph Oroo pe ko wa a ki oun nile lojo Sande naa, nigba tiyen si maa fi de ile won, ko ba Zipporah nile, oun ti won so fun un ni pe o ti lo si oko.
Nigba ti won so pe Zipporah ko tete de, ni Joseph ba bere sii ba Rose soro pe ko fi de, sugbon se loro yi pada nigba ti won so pe Zipporah de, to si bawon mejeeji nibi ti won ti n soro.
Elvis Makori to fisele naa to AWIKONKO leti je ko di mi mo pe Zipporah ko beere ohunkohun to fi bere sii ba Rose ja, to si fa aso ya mo on lorun
Olori agbegbe naa, Maurice Marambe to fidi isele naa mule naa so pe awon araadugbo ti won gbo igbe ariwo ti Rose n pa lo sare loo gba a sile lowo aburo oko e.
Marambe so pe looto ni ko fi be e si oko nita lasiko yi, sugbon sa a, iyen ko so pe kawon obinrin maa ja nitori okunrin, bee lo so pe osibitu Riana to wa nitosi agbegbe naa ni won sare gbe Rose lo fun itoju nitori ti aburo oko e ti fo o lori.
Bakan naa lo tun je ko di mi mo pe boro naa se sele tan ni Zipporah ati oko afesona e ti na papa bora, nitori pe titi dasiko yi lawon olopaa si n wa won.
No comments:
Post a Comment