NITORI FAYOSE, WON TI ILEESE TELIFISAN ATI REDIO IPINLE EKITI PA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, July 15, 2018

NITORI FAYOSE, WON TI ILEESE TELIFISAN ATI REDIO IPINLE EKITI PA

Ajo to n bojuto ero amohunmaworan ati redio lorileede Naijiria, Nigeria Broadcasting Commission (NBC) ti ti ileese telifisan ati redio tipinle Ekiti pa latari asise ti won se lasiko idibo to waye lopin ose to koja, iyen Satide ana.


Ko si nnkan meji to mu ki won ti ileese mejeeji naa pa bi ko se bi won se faaye gba Gomina Ayodele Fayose lati loo kede oludije sipo gomina labe egbe oselu PDP sita pe oun lo jawe olubori lasiko ti won n ka ibo lowo.

Esun naa ti won fi kan won yi ni won loo tapa si ofin to de ileese igbohunsafefe ati ileese amohunmaworan, nitori naa, won ni awon ko tii le so igba ti won yoo si awon ileese mejeeji naa sile.

Asiko ti won so pe ajo eleto idibo nipinle naa n ko awon ibo jo lati mo iye ti won je, ki won si le mo eni to jawe olubori ni won so pe Gomina Fayose lo sibe, to si loo kede Ojogbon Olusola Kolapo gege bi eni to gbegba oroke.

Won ni awon agbegbe merindinlogun kaakiri ipinle naa ni won ti n reti awon ibo tawon araalu di ni olu-ileese ajo eleto idibo naa, ki won le ka won papo, ti ko si tii seni to le fidi e mule ni ajo NBC pase pe ki won ti awon ileese naa pa.

PÍN-IN KÁÀKIRI