KO SI IJA LAARIN EMI ATI ALAYO SINGER MO – SEFIU ALAO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, July 10, 2018

KO SI IJA LAARIN EMI ATI ALAYO SINGER MO – SEFIU ALAO

Ilu mon on ka olorin Fuji nni, Sefiu Alao Adekunle topo eeyan mo si Omo Oko sugbon to loun ti yi oruko inagije oun pada si Baba Oko bayii bayii ti so pe ko si nnkan to n je gege bi ija mo laarin oun ati gbajumo olorin Juju nni, iyen Ayoola Akinola Michael topo awon eeyan mo si Alayo Melody Singer. Sefiu Alao ti won tun n pe ni Kadoso lo soro yi niluu Abeokuta lasiko to n b'AWIKONKO soro ni ofiisi e to wa niluu Abeokuta. Nibe lo ti so pe omo ni Alayo Singer je soun, toun ko si gbodo binu sii. E ka bi iforowero naa se lo.


AWIKONKO: Fun akosile ati aridaju, oruko yin lekunrere?
SEFIU: Oruko mi ni Alaaji Sefiu Alao Adekunle, tawon eeyan mo si Baba Oko.

AWIKONKO: Leyin ASO OLORUN ti e gbe jade, awo-orin yin wo lo tun ti jade?
SEFIU: A ti ni orin nile, sugbon a ko tii fun ni akole, asiko odun Ileya lo maa jade.

AWIKONKO: Se looto ni pe awon Musulumi nikan ni won n ko orin FUJI?
SEFIU: Ko ri bee rara, bi eyin naa ba wo o, awa Musulumi la po ninu olorin FUJI looto, sugbon kii se Musulumi nikan lo n korin FUJI. Orisirisi eeyan lo n ko FUJI, kii se awa nikan. Nnkan to je ki Musulumi po ni pe orin were ti a maa n ko nigba Aawe lo di FUJI, ti e ba si sakiyesi orin Juju, ee ri pe awon Kirisiteeni lo po nibe, nitori pea won to n sise akorin ninu soosi ni won n korin Juju. E tun maa rii pe orin Jesu lo maa n po ninu ori Juju, bee naa ni oro inu Kuraani lo maa n po ninu orin FUJI. Otooto ni, akosejaye awon orin yi lo je ko ri bee.

AWIKONKO: Bawo ni ajosepo yin pelu awon olorin to ku, paapaa awon to sese n dide bo?
SEFIU: Ti e ba sakiyesi, ee ri pe ipade ti a waa se lonii, gbogbo won patapata ni won tu yaya mo mi, ti won n di mo mi, oju mi ko le bi eni to buru, oju mi kii se oju to n le eeyan sa. Oju to fa eeyan mora ni Olorun Oba fun mi. gbogbo won patapata la jo n se. bi eeyan ba se mi, mo maa n pe eni naa si akiyesi lati le je ko tun iwa e se. a si jo maa be ara wa, nibe naa lo maa tan si. Mi o kii mueeyan sinu, nitori ti mo gbagbo pe ise ta n se yi, lati odo Olodumare ni, kii soogun, kii se mimo on se. ise orin kiko je ise ti eni ti Olorun ko ba fi ran, to ba lo n ko, o maa n soro lati je eeyan nidi e. Eeyan gbodo ni ebun e, ko si tun ni oore ofe Olorun.

AWIKONKO: Opo awon eeyan gbagbo pe ija wa laarin eyin ati gbajumo olorin Juju nni, Ogbeni Ayoola Akinola topo awon eeyan mo si Alayo. Se looto ni? E ba wa tan imole sii.
SEFIU: Omo mi pataki ni Alayo Melody Singer, ko si ija kankan laarin wa. Nigba to n se eto idanilekoo Ramadaani (Ramadan Lecture) to koja yii, mo wa nibe. Ile mi lo tun wa ni ojo keji, ta a jo sere. Ko si nkan to da bi ede aiyede laarin wa. Gbogbo eyi to sele koja, ti omo ba se baba e, to ba si ti loo bebe, dandan ni ki baba naa gba fun un. Olorun ko fe eda to ba n mu eda egbe e sinu, Olorun ko si le gba ti iru eni bee. Ko si nnkan to n bo l’oke ti ile ko gba, ile aye la wa. Olorun Oba naa so pe amaa dan ara wa wo pelu buburu ati rere ka too pada wa s’odo e. Iwo ti o o ba ti gba buburu mora, o maa soro lati ri rere. Eni to ba n gba iwosi mora, ti ko binu, ti iwosi naa ba kuro nile, nnkanto dara lo n bo. Bi a se da ile aye niyen. Ko si wahala laarin emi ati Alayo, nitori pe omo mi to dara, to sunmo mi, to sit un nigbagbo ninu mi ni, tie mi naa si nife sii pelu awon toku patapata.

AWIKONKO: Ki le le so nipa egbe olorin PMAN?
SEFIU: Egbe PMAN je egbe to ti wa tipetipe ti gbogbo awa olorin patapata sa si abe e ko too di pe eleyameya bere sii wole de, tonikaluku loo da duor, sugbon bi a se daduro naa, a si n tesiwaju lati maa se egbe yi. Egbe to so gbogbo olorin patapata papo ni egbe PMAN je.

AWIKONKO: Bawo ni ajosepo egbe PMAN pelu awon egbe olorin to ku?
SEFIU: A ni ajosepo to danmonran nitori pe ati egbe FUMAN, ati awon egbe to ku bii egbe olorin Musulumi, inu egbe PMAN la ti n pade ti a ba fee se ipade. Kii se egbe FUMAN nikan lo n ba egbe PMAN se papo, ko da, awon egbe olorin patapata, to fi mo juju ati orin ibile ni a jo wa ninu egbe yii. Egbe PMAN kii se egbe teeyan le foju yepere e, nitori pe egbe to ti wa tipe ni.

AWIKONKO: E ba wa tan imole si ajosepo yin pelu okan lara awon gbajumo sorosoro niluu Abeokuta, iyen Ogbeni Kolawole Adejojo, Kasnaty.
SEFIU: Kolawole Adejojo Kasnaty je omo kan to ti sunmo mi tipetipe, odo Oloogbe Gbenga Adeboye ni mo ti pade e nigbayen. Redio ati awon nnkan ti won fi n tun redio se lo n ta ni Sapon nigba yen. Gbogbo awon ti Gbenga Adeboye ba ti seleri fun lori eto e to maa n se lori redio, odo Kasnaty lo maa n so pe ki won ti wa a pade oun lati gba redio ti won fi ma maa gbo awon eto e. Emi naa maa gbe moto mi to ba pari eto yen, a jo maa lo s’odo Kasnaty ni, lati loo sere. Kasnaty je omo kan to farabale daadaa. Oun gan an lo nife mi, nitori pe Kasnaty lo fi ife han si mi. Igba to fi ife han si mi, lemi naa fi ife han sii pada, temi naa si n se daadaa pelu e.

AWIKONKO: Amoran yin fawon araalu, paapaa nipa orin FUJI?
SEFIU: Mo fe e je kawon araalu mo pe orin FUJI je orin isembaye ti a n fie de Yoruba ko, orin FUJI je orin pataki to ti wa lati odun to ti pe ni. Lati ori orin kan de orin min in ni orin FUJI je, paapaa gbogbo awon ohun elo to n mu orin dun ni won n papo mo FUJI, tawon eeyan si n gba ti e. FUJI je orin kan ti a gbodo maa gbo, to je bi awon araalu gan ba rii ti olorin FUJI ba se asise, aaye wa lati pe won si akiyesi, ki won si gba won nimonran, ki won ba won soro. Orin ti gbogbo eeyan nifesi ni orin FUJI. Awon Ibo ati Awusa gan an gbo orin FUJI, ayafi eni ti ko ba si Eko ninu won ni ko nii mo nnkan to n je orin FUJI. Mo sit un dupe lowo awon baba nla wa bii Barrister, Kollington, Wasiu Ayinde ti won s’agbekale e. Ki Olorun ko si ba wa da emi awa taa wa laye sii, ki Olorun si ba w ate awon to ti ku si afefe rere.

PÍN-IN KÁÀKIRI