Ibeere yi fe mi leyin, sugbon mo ni lati so
o. Emi gege bi enikan, mo feran ki okunrin gaa, ko si je olotito to tun ni iwa
irele bi adaba. Mo gbodo ri okunrin yen gege bi eni to ni iberu Olorun l'okan,
ki iwa tutu e si je lati okan wa. Ti m ba ti ri iru awon iwa bayii, ko si nnkan
to ni ki n ma gba fun un.
- Agbejoro Maryam Adenle (Eka DPP, Ibadan,
Oyo)
============================================================
Ni temi o, ki n too le gba fun okunrin to ba
ko enu ife si mi, maa koko wo iduro e daadaa, maa wo bo ba se ri. To ba je pe o
dun un wo l'omokunrin, ti mo si rii gege bi eni ti kii fa wahala, to je bii
eeyan jeje. Ma a koko wo iwa e fun bi ojo meloo kan, to ba n pe mi deede, to si
n ba mi so awon oro to le yi igbesi aye eeyan pada si rere. To ba n se deede,
ti mo si rii gege bi eni to ni iriri. Ko si nnkan to ni ki n ma gba fun un.
- Blessing, Abeokuta
============================================================
Mo feran okunrin to beru Olorun ati pe ko je
olotito eeyan, sugbon eyi to ju nibe ni pe ki okunrin je oluberu Olorun ati
olotito eeyan nitori pe igbagbo mi ni wi pe ewa ara kii se ohun ti yoo maa wa
lo titi. Bakan naa, bi okunrin ba ni owo lowo, ti ko ni iwa, asan ni, nitori pe
iwa rere ati otito kii fi eeyan sile.
- Muhammad Morufat Osise Ijoba Ibile
nipinle Oyo
============================================================
Oruko mi ni Omidan Olayiwola Titilayo
Baleeqiz. Mo je onimo nipa bi a se n ko ile. Nipa ti ibeere ti e bi mi yii,
emi gege bi enikan, mo feran ki okunrin ni ewa, ko si je olotito ati oluberu
Olorun. Ko si tun je eni to ni igboya lati doju ko ohunkohun, bi okunrin naa ba
ko enu ife si mi, dandan ni fun mi ki n gba fun.
- Omidan Olayiwola Titilayo Baleeqiz
============================================================
Ajibola Yetunde
loruko mi, lati ipinle Ondo. Emi gege bi enikan, paapaa bi eyin naa se ri mi
gege bi oniwa tutu, ki n too le gba fun okunrin to ba ko enu ife si mi, o gbodo
jade lati idile rere nitori pe awon Yoruba maa n so pe oko buruku se e fe, ana
buruku ni ko see ni. Eleekeji ni pe, o gbodo je okunrin to mo bi won se n toju
obinrin, o si tun gbodo ni owo lowo, nitori pe gbogbo wa la mo pe owo ni Keke
ihinrere.
- Ajibola Yetunde,
Ondo
===============================================================
Ni temi o, emi o
le tan ara mi je. Ki n too le gba fun okunrin to ba ko enu ife si mi, mo gbodo
rii pe iru okunrin bee wa lati idile rere, ti won si lowo lowo, to si le ran
ipo ti mo wa lowo. Mo tun gbodo rii gege bi okunrin to se e mu yangan lawujo,
kii se pe maa fe jade, mi o ni le so pe ka jo jade, tabi ko loun fe e mu mi
jade, ki n wa maa sa seyin. Mai dia ma binu, oo ni le tele mi ko s'oja, tabi
kiloobu, ti m ba de, a ma maa soro, ko joo rara, ko le sise. Eleeketa ni pe, o
gbodo ni iwa to daa, ki iwa awa mejeeji si ba ara wa mu. Ko ju bee lo.
- Lade Omolade,
Ondo
===========================================================
Hmmmmm! O gbodo je
eni to ni iwa tutu, o gbodo je eni to n se deede, ti kii paro, to si tun maa n
mu ileri tabi awon oro e se. O gbodo je eni to n ni suuru to po, ko si mo bi
won se n toju obinrin. Bakan naa, o tun gbodo mo bi won se n se aponle obinrin.
- Okolie
Habibat, Delta
===========================================================
Ki n to le gba fun
okunrin kan gege bi oko afesona, o gbodo je oniwa tutu, o gbodo je eni to mo
oro o gbo daadaa, eyin to n farabale gbo oro, tii kii se oniwa jau-jau. Kii se
okunrin to kan je pe o kan ma maa binu lai ni idi kan ni pato, mi o le gba fun
okunrin to baa n da eero okan se. Iru okunrin bee tun gbodo le je eni to niberu
Olorun. O gbodo ja fafa, ko ni imo ati oye awon nnkan daadaa, ko si mo iwe, kii
se pe ti a ba fe ara wa tan, ko wa a di pe awon omo wa n gbe ise amurele (Home
Work) wa sile lati ileewe, ko wa maa so pe mama ni ko loo ba. O tun gbodo je
eni to le duro figagbaga laarin awon eeyan lawujo, kii se pe ko ma le baayan se
po. Ko gbodo je eni to ma maa kalolo bi won ba pe e pe ko waa soro nibikan.
- Busari
Oluwaseun, Ago-Iwoye
===========================================================
E seun o. Emi o,
ni temi o, ki n too le gba fun okunrin gege bi oko afesona, isesi e nigba to
koko pade mi lo maa je ki n mo boya maa gba fun tabi mi o nii gba fun, ati pe
ti a ba n ba ore wa lo, awon iwa ni ma maa wo, bo ba se n se si mi, ti iwa ba
ba ti temi mu, maa duro, ti ko ba si ba temi mu, a je pe a maa ja pa niyen.
Lasiko ibadore (relationship), bi oko tabi iyawo ba n pa iro, iru ibadore bee
kii pe ko too tuka. Eleekeji, nnkan ti okunrin ko ba to, ko gbodo so o, nnkan
ti ko ba si le se laarin odun marun un, ko gbodo maa fi buga pe oun le se e
lesekese. Igbora-eni-ye naa tun se pataki, a gbodo le gbo oro si ara wa lenu,
ka si le ba ara wa gba imonran papo.
- Adurotimi
Catherine Afolasade, Mapoly Abeokuta.
No comments:
Post a Comment