Beeyan ba ri bi
iyaale ile kan, Arabinrin Sherifat Taiwo se n kunle be ile ejo kokokoko to wa
ni Ake Abeokuta lojo Tusde ose to koja yi pe ki won ba ou8n tu igbeyawo to wa
laarin oun ati oko oun, Hassan Taiwo ka, nitori pe iwa e ko ba toun mu mo rara
yoo mo pe ija lo de ti orin d’owe.
Bo tile je pe
baale ile naa, Hassan ko yoju si kootu lojo naa, ti Sherifat naa ko si so iye
odun toun ati oko ti n ba ife won bo, sugbon oro to n so fi han daju pe iya n
dagbe lobinrin naa fe maa se.
Sherifat so pe
“Kii se pe bo ya mo fe e lo l’oko min in ni mo se fe e ko oko mi sile, sugbon
mi o tii ri iru okunrin bi oko mi ri nitori pe bukata ile ko joo loju, kii
bikita si alaafia emi atawon omo mi. e ma je ki n tan yin, emi ni mo ko ile ta
a jo n gbe, ti mi o si fin ii lara rara, pelu ife ni mo fi n baa lo po.
“Lojo kan ni oko
mi wa a ka mi soobu pelu ore e kan, to si bere sii lu mi mo 'be. O tun loo so fun
baba to gbe soobu fun mi pe ko le mi danu ninu soobu naa, ko si gbe e f'elomin
in.
“Eyi to tun maa
n kan mi lominu ni pe gbogbo awon omo ti mo bi fun un kii gbe seyin mi, eyin
baba won ni gbogbo won n wa, o ti e to abikeyin omo mi, kii fe e gbo pe mo soro
baba won laid a rara. E saanu mi Oluwa mi, mi o loko mo o.”
Ibi ti Sherifat
soro de re ti Oloye Akande O. O to je Aare ile ejo naa ti so pe ko si gbenu e
dake naa nitori pe oko e to n fejo e sun ko si ni kootu, nitori naa ko loo fun
oko e niwe pe kootu fe e ri lojo kerinla osu ta a wa yii.
No comments:
Post a Comment