FIJILANTE IPINLE OGUN BERE ETO AABO LORI REDIO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, July 17, 2018

FIJILANTE IPINLE OGUN BERE ETO AABO LORI REDIO

Fijilante ipinle Ogun, iyen Vigilante Service of Ogun State (VSO) labe oga agba, Olusoji Ganzallo ti bere eto aabo lori redio Paramount 94.5FM, eka ileese redio Naijiria to wa niluu Abeokuta.


Laarin aago meta si aago meta aabo osan gbogbo ojo Wesde ni eto naa ti won pe ni 'Aabo Terutomo yoo maa waye. Ori eto naa la gbo pe won yoo ti maa yanna-naa bi eto aabo se n lo si kaakiri ipinle Ogun, ti won yoo si tun maa so ojuse araalu nipa eto aabo.


AWIKONKO gbo pe agbenuso fun egbe Fijilante tipinle Ogun, Ogbeni Moruf Kolawole Yusuf ni yoo maa dari eto naa, ti yoo si tun maa so awon ise ti won n se ni gbogbo igba.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI