Komanda Olanrewaju Nureni Adedoyin to je oga agba egbe VGN nipinle Ogun ti bawon araalu Abeokuta, paapaa awon ti won pada ebi won ati dukia won sinu ijamba omiyale to sele lojo Fraide to koja yi.
Adedoyin so pe ibanuje nla lo je foun nigba toun ri bi agbara wo opolopo dukia lo, to si tun fi aimoye emi sofo danu.
Ninu atejade to fi ranse s'AWIKONKO laaro onii lo ti je jo di mi mo pe isele naa je eyi to bani lokan je pupo pelu bi opolo emi ati dukia to ni bilionu naira se sofo danu, to si tun so opo eeyan di alaini ile lori mo.
O ni bo se je pe lara nnkan ti egbe naa wa fun ni lati maa daabo bo agbegbe kaakiri awon ipinle lorileede Naijiria, sibe, awon yoo tubo maa dahun gbogbo ipe pajawiri tawon araalu ba n pe won si.
Bakan naa lo dupe lowo gomina Ibikunle Amosun fun ti awon opopona to se kaakiri ipinle Ogun, paapaa ilu Abeokuta, eyi ti ko je ki isele naa koja soso, nitori pe awon kota ti omi n raaye gba koja lo tubo je ki isele naa mo niwonba.