EYI NI BI DOKITA ATI NOOSI SE PA ALABOYUN NIPINLE OGUN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, July 30, 2018

EYI NI BI DOKITA ATI NOOSI SE PA ALABOYUN NIPINLE OGUN


Ka ni ogbeni kan ti won pe ni Olawale Raji mo pe ise oyun toun fe e se fun arabinrin kan ti won pe oruko e ni Aminat Iyanda Atisola mo pe ise naa ni yoo ran oun lo si ogba ewon ni, o see se ko ti ye e, tabi pe ko so fun Bose naa pe ko lo si osibitu min in loo yo oyun naa.

Gege ba a se gbo, agbegbe Atan-Ota ni won ni Aminat to wa nile oko lo o ba Olawaji Raji ti won nise dokita lo n se pe ko ba oun yo oyun osu meji to wa lara oun, iyen ni ose to koja yi.

AWIKONKO gbo pe kaka ki Olawale so pe ki Aminat wa a ba oun ni osibitu, ki won le sise abe lati yo oyun naa, se loo so pe ko maa lo sile, toun yoo wa ba nile lati sise abe yiyo oyun naa.

Won ni Olawale ati Olusegun Funmilayo ti won noosi loun n se ni won jo lo si ile Aminat pelu awon irinse ti won fi n yo oyun, igba ti won n yo oyun naa lowo la gbo pe oro fe e yiwo mo won lowo.

Bi won se so pe agbara won ko fe e gbe oyun yiyo naa, lo je ki won pinnu lati gbe Aminat lo si osibitu ijoba apapo to wa ni Abeokuta, iyen FMC to wa ladugbo Idi-Aba lati le doola emi e.

Oju ona la gbo pe Aminat dake si ninu moto ti won wa, eyi gan an lo fa a tawon dokita FMC fi so fun won nigba ti won de be pe oku eeyan ni won gbe wa, nitori naa, awon ko le gba a.

Eyi gan an ni won loo bi egbon Aminat, Arabinrin Bose Kazeem ti won lo n gbe lojule kefa, adugbo Ireakari, Atan-Ota ninu to si gba tesan olopaa lo lojo kerindinlogbon lati fi ejo sun.

Lesekese la gbo pe awon olopaa Ota naa ti gbera lati loo mu Olawale ati Funmilayo fun bi won se pa Aminat lasiko ti won n yo oyun fun un.

Bi iroyin naa si se te Ahmed Iliyasu lowo lo ti pase pe ki won gbe won lo si eka ileese olopaa to n ri si iwa odaran, iyen Zone 2 niluu Abeokuta lati tesiwaju ninu ise iwadii.

A tun gbo pe oku Aminat ti won lomodun metadinlogoji ni lo si ti mosuari fun ayewo

PÍN-IN KÁÀKIRI