Asiri Daniel to fipa ja ibale omodun mefa tu - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, July 2, 2018

Asiri Daniel to fipa ja ibale omodun mefa tu

Kani kii se pe awon olopaa Ajuwon tete de adugbo Olufemi Oshin to wa ni Alagbole Akute nipinle Ogun lojo Tusde ose to koja yi, o see se ki won ti lu gendekunrin eni odun merindinlogbon (26), Daniel Essien pa, ki won si tun dana sun soobu e to ti n sise geri-geri (barber) latari bi won se fesun kan an pe o fipa ja ibale omodun mefa, to si tun n ko ibasun fomo naa karakara.

AWIKONKO gbo pe eemeta otooto ni won so pe Essien ti ba omodun mefa naa ta a foruko bo lasiri sun pelu bo se maa n fi bisikiiti tan an pe ko gbodo so fenikeni, ati pe se loun yoo luu lalubami to ba fi le soro naa jade.

Nigba tomo naa de ileewe lojo Monde la gbo pe Tisa e bere sii beere orisirisi ibeere lowo awon omo kilaasi nikookan, nigba to si kan omo yi, lo ba jewo pe buoda kan to n sise agerun to wa ladugbo awon maa n ba oun sun karakara, to si maa n dunkoko moun pe oun ko gbodo so o sita.

Tisa naa la gbo pe o pe Arabinrin Ayoola Tolulope to je iya omo naa lori foonu pe ko bojuto omo e daadaa nitori pe o jewo foun pe buoda kan maa n ba oun sun ladugbo.

Tolulope nigba to gbo oro yi ni won ni ara e ko ti bale, to si je pe se lo ni won je ki omo oun maa bo nile lesekese, sugbon ti Tisa naa ni afigba tawon ba jade lomo naa too le kuro nileewe.

Komo naa too de la gbo pe Tolulope ti bere sii royij nnkan ti eti e gbo nipa omo e fawon eeyan, paapaa awon ti won jo n gbe ni ojule kefa adugbo naa, bi omo naa si se n wole loun naa ti beere eni to je, to si daruko pe Essien leni naa.

Eyi lo mu ko loo pariwo le Essien ti won ni oloju komu-o-lo ni, ko seni ti ko le ko enu fife si, sugbon to yari kanle pe won fe e ba oun loruko je, ta a si gbo pe awon eeyan ti bere sii gba leti, tawon kan tun fe e dana sun un pelu soobu e.

Awon araadugbo naa la gbo pe won ni ki Tolulope loo foro e to awon olopaa leti, tawon yen naa si tele loo mu Essien. Bo tile je pe se ni Essien so pe iro ni won pa moun, sibe ayewo ti won mu omo naa lo se ni osibitu kan lojo Tusde fidi e mule pe looto ni won ti n ba omo naa sun.

Eyi lo mu ki Essien bebe pe looto ni, ati pe ise esu, nitori naa ki won se oun jeje, ki won ma si se ran oun lo sewon.

Komisana olopaa, Ahmed Iliyasu boro naa se too leti lo ti ni ki won tare e sodo eka ileese won to n ri si fifomo soowo eru, iyen SCIID lati tubo sewadi, ki won le foju e bale ejo bi otito oro ba ti jade.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI