Bi iroyin to te AWIKONKO lowo lai pe yi ba fi le je otito, a je pe egbe oselu APC nipinle Ogun labe gomina Ibikunle Amosun ni ise pupo lati se lori ba a se n fojoojumo gbo pe awon egbe naa ti n fibinu yo ara won kuro ninu egbe.
Gege bi a se gbo, ojo Tusde to koja yi la gbo pe Onarebu Oladipupo Adebutu to n soju ekun Remo nile igbimo asoju-sofin niluu Abuja loo se abewo si Alaye tiluu Ayetoro, Oba Azeez Adelakun (Akinola II), nibe naa lo tun ti bawon omo egbe oselu PDP to wa layika ati agbe naa se ipade po.
AWIKONKO gbo pe nibi ipade naa lawon omo egbe oselu APC ti won wa nibe ti sare wa pe kawon wa a satileyin fun Onarebu Oladipupo Adebutu to je omo gbajumo onisowo nni, Adebutu Keshington fun idibo gomina odun 2019.
Ogbeni Muyideen Alao ti won loo je okan lara awon igi leyin ogba fun egbe oselu APC niluu Ayetoro la gbo pe o lewaju awon omo egbe lati loo so pe egbe PDP ti Onarebu Adebutu tawon eeyan tun n pe ni LADO fe e gba jade lawon tun fe e tele bayii.
Awon omo egbe oselu APC ti ko din ni egberun meji la gbo pe won fa kaadi egbe won ya, ti won si n so pe awon ko le tele gomina ipinle Ogun, Ibikunle Amosun mo, nitori pe o ti dale awon.
AWIKONKO gbo pe ohun tawon eeyan naa n so ni pe lati odun meje seyin ti gomina Amosun ti depo lo ti se ileri fun won pe oun yoo tun awon ona won se, toun yoo si tun mu awon nkan amayederun wa fun won, sugbon to je pe oro ori ahon lasan ni.
Ogbeni Muyideen Alao gege ba a se gbo so pe oun ko le se oju meji mo, nitori e loun se pe awon eeyan oun lati wa a satileyin fun LADO, ki ipinu e le wa si imuse.
Nigba to n soro, Onarebu Adebutu dupe lowo awon eeyan naa fun ife ti won ni sii, ati bi won se lawon fe e satileyin fun lodun 2019. LADO wa a seleri fawon eeyan naa pe oun ko nii fi eto won dun won gege bi gomina ipinle Ogun se fi n dun won lateyin wa.
Bee lo gba won nimoran pe ki won tete loo gba kaadi idibo alalope, iyen PVC won ko too pe ju, nitori pe oun nikan naa ni agbara ti won ni lodun 2019.
No comments:
Post a Comment