Lonii ojo Isegun, Tusde lawon omo eyin Yayi
legbe oselu APC ti ko din ni egberun lona ogun (20,000) loo darapo mo egbe
oselu Alliance for Democracy, AD latari awon iwa aibikita ati ilodi si isejoba
awaarawa ti won so pe Gomina Ibikunle Amosun tipinle Ogun n hu fawon.
Won ni awon ko le farada iya ti Gomina Amosun
fi n je awon mo, nitori naa lawon ko se le tesiwaju lati maa se egbe APC naa
mo, ati pe egbe oselu AD tawon ti kuro tele lawon setan lati pada si bayii.
Gege bi AWIKONKO se gbo, Onarebu Kunle
Adeshina to je alaga egbe awon alenu-loro ninu eto isejoba, iyen De-Democrat ni
won loo siwaju awon omo egbe naa to n se ti Seneto Olamilekan Adeola, iyen Yayi
lati loo sepade pelu awon oniroyin nipinle Ogun ninu ogba ileese won to wa ni
Iwe-Irohin, Oke-Ilewo pe awon ti darapo mo egbe oselu AD bayii.
Ohun ta a gbo ni pe awon eeyan naa ko fee
pada segbe oselu APC ti won n se tele mo nitori awon iwa aibikita ti won so pe
Gomina Amosun n se, bee ni won tun so pe ijoba amunileru ni Amosun n se fawonninu
egbe, paapaa nipinle Ogun.
Nigba to n soro, Onarebu Adeshina so pe “Egbe
De-Democrat je egbe awon omo egbe oselu APC to jade kuro ninu awon to n se ti
Seneto Yayi gege bi awon iwa aibikita eto oselu awaarawa ti Gomina Amosun n se.
“A ni awon omo egbe to le ni egberun lona
ogoji (40,000) kaakiri woodu igba ati merindinlogoji (236 wards) lawon ijoba
ibile ogun to wa nipinle Ogun. Egbe De-Democrats ti wa lati bi odun meji le die
seyin, to si je ninu awon egbe oselu bii PDP, SDP, UPN atawon egbe oselu min in
lawon ti ni omo egbe, tawon si jo ni afojusun kan naa lati gbaruku ti Seneto
Solomon Olamilekan Adeola (Yayi) lati dije dupo gomina ipinle Ogun.
“O seni laanu pe won ti yo ese omo egbe
tuntun naa kuro lawo lati kopa ninu egbe oselu APC latari iwa ilodi si isejoba
awaarawa ti ogbeni Gomina n hu. O se pataki lasiko yi lati so pe Yayi ti pinu
lokan ara e lati yeba kuro nibi idije ipo gomina ipinle Ogun lati le ma je ki
wahala sele ninu egbe APC.
Siwaju si lo tun so pe “Lojo keji osu kejo
odun 2017 la sepade awon oniroyin tawon agbaagba egbe De-Democrat nipinle yi ti
pe akiyesi awon agbaagba egbe oselu APC sawon iwa ilodi si eto isejoba awaarawa
(undemocratic practices) ti Gomina n hu, to si je pe opo awon iwe iroyin ni gbe
e.
“Bakan naa la tun fi leta ranse si alaga egbe
oselu APC lorileede yi, Oloye John Oyegun lati so awon ipele ti Amosun ti ba
egbe naa je de. Awon igbimo eleni ogun ni won loo fun igbakeji alaga naa,
Onimo-ero Segun Oni. Ojo keje osu kejo odun 2017 lawon iwe iroyin meji gbe e
jade.”
Nigba to n kadi oro e nile, Onarebu Kunle
Adeshina wa a rawo ebe sawon omo ipinle Ogun pe ki won fowosowopo peluu won
lati gbaruku ti egbe oselu AD nitori pe oun nikan ni egbe to le mu eleyameya
kuro nipinle Ogun, ti ko si nii gba iwa aibikita tabi eleyameya laaye bii ti
Gomina Amosun.