Agbejoro to fe e fipa gbowo abetele d'ero atimole - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, July 2, 2018

Agbejoro to fe e fipa gbowo abetele d'ero atimole

Ni nnkan bi aago marun aabo irole ojo Fraide to koja yi nileese olopaa ipinle Ogun foju awon odaran mefa kan ti agbejoro naa wa lara won han fun die lara awon oniroyin, eyi ti akoroyin Oodua naa pelu won logba SARS to wa ni Magbon, Abeokuta.

Gege bi ohun ta a gbo, won ni okunrin onisowo kan ti won poruko e ni Alaaji Sakirudeen Olufowobi to n gbe ni Imagbon, Ijebu Ode lo loo fesun kan awon kan pe won n lepa emi oun, won si n beere owo lowo oun lati fi ra emi oun pada.

Awon min in towo tun te ni: Adeborode Ogunlaja, Sodiq Owolabi, Abolaji Alabi, Mukaila Abolaji, Abiodun Adebayo ati Abolaji Adebola.

AWIKONKO gbo pe ko too di pe awon eni ibi yi bere sii dunkoko mo Alaaji Olufowobi, awon adigunjale kan ti wonu oko e to da, ti won si ji gbogbo awon ere oko e lo, sugbon tawon olopaa sewadi e, ti won si rowo to won.

Alaaji naa la gbo pe o tun so fawon olopaa pe ki won fawon adigunjale naa sile nitori pe adugbo kan naa lawon jo wa, toun ko si nii fe ki won so oun lenu.

Leyin tawon olopaa fi won sile la gbo pe won bere sii dunkoko mo Alaaji yi pe ko loo mu 250milionu naira wa to ba ni emi e lo, toun naa si loo foro naa to awon olopaa leti pada.

Awon towo tun te
Abimbola Oyeyemi to je agbenuso fawon olopaa nigba to n soro so pe asiri awon eeyan naa tu nigba tawon bere ise otelemuye, tawon si gba ohun gbogbo won sile pelu bi won se n dunkoko lati gba owo lowo Alaaji Olufowobi, eyi ti agbejoro naa wa laarin won.

O niyalenu lo je pe amofin naa tun wa laarin won, iyen eni ti won loun gan an lo mu aba naa wa pe ki won dunkoko mo lati gba owo lowo e lai mo pe bi nnkan se n lo lawon n ni akosile.

Oyeyemi so pe oun ti beere lowo e pe se looto lo je ojulowo agbejoro, o si so pe beeni, ti mo si rii pe otito lo je agbejoro, sugbon nigba tawon ba dele ejo, yoo so nnkan to ri l'obe to fi wa iru sowo, to fi n lu jibiti.

Bakan naa lo tun ni agbejoro naa tun pelu awon ledi apo po pelu pasito kan to n fi ayederu ise Iyanu lu awon eeyan ni jibiti, ti won ko si san owo feni ti won lo fun ise Iyanu naa, iyen eni ti won ni ko so ijapa mo ikun.

Nigba toun naa n b'AWIKONKO soro, agbejoro naa, Kayode Oshinyemi (Esq) so pe iro ni won pa moun nitori pe oun ba enikeni duna dura owo, ati pe oun ko le soro pupo ayafi tawon ba dele ejo, ki onikaluku si so tenu e, ati pe ile ejo lo te oun lorun lati soro.

Oshinyemi so pe awon ti koko gbe ejo kan lo si kootu to nii se pelu bi Alaaji yi se ran awon soja lati loo lu onibara oun kan, Abolaji Adebola Mukaila to si je pe ninu iwe esun tawon fi kan an ni kootu lawon ti ni ko san owo gba mabinu, to si wa ninu akosile iwe to wa nile ejo.

Adebayo
Abiodun Adebayo to nise jibiti loun n lu so pe ore oun kan, Korede Ogunlana lo gbe ise kan foun pe koun wa loo so ijapa mo ikun ninu soosi lati le je ki pasito kan to wa ni Ilese le fi sise iyanu pe ti won ba ti pe eni to ni emi okunkun lara, koun jade sita lati fi ya awon eeyan lenu, ki won le so pe pasito naa ni emi Olorun looto.

O so pe leyin toun pari ise naa, to ku ki won foun lowo ni won ti bere sii yi oun sotun-sosi, ti wok ko si foun titi dasiko yii. Igba to ya ni won tun wa a ba oun pe kawon wa a lo ji enikan gbe, nigba ti won juwe eni yen loun rii pe okan lara awon baba alaanu oun ni, iyen Alaaji Olufowobi.

Nibe loun ti so pe oun ko le se, ki won lo wa elomin in nitori pe eni mimo oun ni, bee lo so pe lesekese loun ti gba ile Alaaji naa lo lati loo fi too leti pe ko fura nitori pe awon kan n pinu lati kii gbe.

Adebayo niyalenu lo je foun nigba toun ri awon olopaa SARS ti won wa a gbe oun lojo Fraide naa pe koun wa a lo tun oro toun so fun Alaaji naa so, nnkan to loo gbe oun de ogba SARS niyen.


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI