Yeepaaa: Amudalat ju omo e sinu salanga - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, June 25, 2018

Yeepaaa: Amudalat ju omo e sinu salanga


Kayeefi loro odomobinrin eni odun mokanlelogun kan, Amudalata Taiwo ti won loo ju omo e, omo ojo mejila sinu salanga. Ojule kkejidinlogun, adugo Isheri niluu Ilaro la gbo pe Amudalat to ju omo e sinu salanga yi n gbe, ojo Wesde to koja yi nisele naa waye.

Amudalat
Gege b’AWIKONKO se gbo, won ni Amudalat so pe oun ko le toju omo naa lo mu koun ronu lati loo ju sinu salanga, ati pe baba omo naa to foun loyun ko toju oun bo ti to ati bo ti ye.

Ohun ta a gbo ni pe Owolabi taiwo to fun Amudalat loyun ti feyawo kan tele, tiyen si ti bimo marun un fun, sibe won ni oloju komu-o-lo ni Owolabi, idi ni yii to tun fi ki Amudalat mole, to si fun un loyun.

AWIKONKO gbo pe laaro kutu ogunjo osu yi ni Amudalat dide kuro lori beedi, nibi to sun si, to si gbe omo naa dani lo si salanga won to wa leyinkule ile to n gbe, ariwo omo kekere naa la gbo pe baba onile, Ogbeni Oshunshina Olawale gbo to fi taji.

Omo naa
Bi Olawale si se gbo ariwo igbe omo yi lo mu ko loo wo nnkan to n sele, nigba to si maa de ibi to ti n gbo ariwo, Amudalat lo pade loju ona, ti ko si ri omo lowo e, lesekese lo ti beere omo to gbe dani, sugbon ti ko ri nnkan so.

Igba ti Amudalat ko tete da Olawale lohun lo ba pariwo sita pe kawon eeyan wa a wo nnkan to n sele, nibe lo ti jewo fun won pe oun ti ju omo naa sinu salanga.

Awon to gboro naa ko duro ti won fi loo fo salanga yi, ti won si yo omo naa jade. Olawale la gbo pe o gba tesan olopaa to wa niluu Ilaro, ti won si gbe Amudalat lo si olu-ileese olopaa to wa ni Eleweran niluu Abeokuta.

Nibe ni won ti pase pe ki won loo mu baba omo ti Amudalat ju si salanga wa, igba ti won muu de ni Komisana olopaa, Ahmed Iliyasu pase pe ki won tare e si Zone 2 nitori pe oun ni ko toju iya omo naa, iyen Amudalat.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI