WON SO OGA NEPA LOKUTA PA L'OTA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, June 12, 2018

WON SO OGA NEPA LOKUTA PA L'OTA


Bo tile je pe oro naa ti wa nile ejo Majisireeti to wa ni Ota nipinle Ogun, sibe titi di bi e ti n ka iroyin yi lawon ebi Oloogbe Ogbeni Peter Ayole ti won so pe okan lara awon oga NEPA ni ko tii le gbagbe iku to pa a.

Ni nnkan binaago mejila aabo osan ojo Wesde ojo ketalelogun osu karun to koja yi la gbo pe awon kan ti won wa nitosi ile e keji tonn ko lowo l'Ota so okunrin, eni odun mejilelaadota (52) pa latari ede aiyede to sele laarin won.

Gege b'AWIKONKO se gbo, won ni ileese kan to wa legbe ile e naa to ti fe e ko pari ni won maa n tan ero amunawa jenereto, ti eefin jenereto naa si maa n dawon laamu, paapaa ladugbo.

A gbo pe inu ogba ile Peter ni won dori eefin naa ko, to si ti bawon soro lopo igba pe ki won wa ona bi won yoo se yi ibi ti eefin naa n gba jade kuro lodo e, sugbon ti won so pe awon yen ko gbo si lenu.

Ose to lo.lohun ni won so pe Peter to je akowe owo (auditor) fun ileese Enugu Electricity Distribution Company to wa niluu Abakaliki ni won so pe won fun un ni aaye isinmi ramps, to si wa sile e lati wa a sinmi lodo awon ebi e l'Ota.

Won ni laaro ojo tisele buruku naa waye, oun at iyawo e, Arabinrin Oluwafunmilayo Akole ni won jo wa ninu ile laaro ojo naa ko too so pe oun n lo sile e keji tawon osise (plumber) ti n sise lowo.

A gbo pe ko tii ju ogbon iseju lo ki won too ranse pe iyawo e pe won ti so okuta pa oko e, to si ti gbagbe soda sorun alakeji.

Lesekese la gbo pe obinrin naa ti sare loo wo nnkan to n sele, ko da a ti won so pe ko duro wo Bata, nigba to si maa de be, oku oko e Peter lo ba nibi ti won te e sii.

Won so pe nigba ti Peter de be lo rii pe awon to n ba sise ko sise, to je pe ere ni won n se, eyi lo muu fibinu soro si won pe ki lo n dawon duro, tawon yen si dahun pe awon ko le sise ninu eefin, ayafi binwon ba pa jenereto to n da eefin sile.

Ibinu ni won so pe Peter fi mu igi kan, to si gun bulooku meta nibi ti jenereto naa wa, to si bere sii gba a, ariwo ti won lawon osise ogba naa gbo lo mu won yoju, ti won sinrii pe Peter lo wa nibe.

Se lo dabii pe won ti reke Peter tele ni, to mu ki won bere sii ju okuta luu titi to fi jabo lori igi to gun, ori ni won loo mu lo sile, to si dagbere faye pe o digbose.

Gbogbo bi won ni won se n gbe kaakiri osibitu ni won n ko o pe awon ko le gba a nitori pe o ti fake, eyi lo mu ki won gbe e pada sile, nigba ti won si maa gbe dele, eje ti n jade loju, ati, imu ati enu e.

Won ji ko tii ju ogbon iseju ti won pada dele lo lawon olopaa kan lati Onipaanu yoju pe won wa fejo Peter sun pe ko je kawon araadugbo gbadun, to si tun n da alaafia won laamu, ati pe awon fe e ri lago awon lati wa a towo bowe, sugbon iyalenu ni won loo je fun won nigba ti won ba oku Peter nile, ti won si ni kiyawo e tele won de tesan lati towo bowe to ye ki Peter oko e to doloogbe towo bo.

Leyin naa ni lawon olopaa tun pada ko awon marun tinwon loo fejo sun ni tesan pe awon gan an ni won pa Peter.

Awon marun naa ni: Morenike Akinleye, eni odun metalelogoji (43); Ajah Chijioke, eni odun merindinlaadota (46); Sulaimon Akinleye, eni ogbon odun (30; Bose Adebesin, eni odun merinlelogun (24) ati Nurudeen Adekunbi toun je omo ogun odun (20).

Esun apaayan si ni won fi kan won ni kootu, eyi ti won loo tako ofin odaran tipinle Ogun todun 2006 to wa ni abala 324.

Bo tile je pe agbejoro awon odaran naa gbiyanju pe ki adajo faaye sile fun beeli, sugbon ti adajo naa, J. A. Akan so pe ko si aaye fun beeli won, to si tun sun igbejo min in dojo kesan an osu keje to n bo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI