Won lawon SARS le Awilo pa l'Abeokuta - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, June 25, 2018

Won lawon SARS le Awilo pa l'Abeokuta


...Iro ni o, bo se je gan an re e - Ogbeni Adeyemi

Beeyan ba de Tamaaki (Tarmac) Ibara ti won ti n ta foonu niluu Abeokuta lojo Tusde ati Wesde ose to koja, to rii bawon omo egbe oni foonu se roju koko, yoo mo pe inu won ko dun lori okan lara awon omo egbe, Emmanuel Sunday Opeyemi tawon ololufe e tun n pe ni Awilo, to doloogbe lojo Aje Monde ose to koja yi.

Bo tile je pe orisirisi lawon eeyan n gbe kaakiri ohun to sokunfa iku Awilo ti won lojo ori e ko tii ju odun metadinlogbon (27) lo, nitori bawon kan se n so pe ibi tawon SARS ti n le lo ti jabo si kota, bee lawon kan n so pe se ni won yinbon fun un.

Ohun ta a tun gbo ni pe lose to.lo lohun lawon olopaa SARS atawon eso ologun jo fa wahala, nitori ti won ro pe omo Yahoo ni won, nibe ni won lawon kan ti loo da si lati tako awon SARS, toro naa si di isu ata yannyan.

Eyi lo fa ti won lawon SARS naa fi pada wa laaro kutu ojo Monde lati wa a doju ko awon to di won lowo lojo naa, ti won si gbagbo pe lara awon to n ta foonu ni. Won ni nibi ti won ti n le awon eeyan ni Awilo naa ti n salo, to si loo faya lu irin, to si ku lesekese.

Sugbon lati fidi isele naa mule ko je ki AWIKONKO teko leti lo si Tamaaki naa lati loo fidi e mule lojo Wesde, ohun tawon to b'Alariya Oodua soro so ni pe awon ko le fidi isele naa mule nitori pe awon ko gbo nipa iroyin ti won n gbe kaakiri.

Ko da, nigba toun naa n b'AWIKONKO soro ninu ofiisi e, Komureedi Adesesan Adeyemi to je alaga egbe awon to n ta foonu ni Tamaaki naa so pe aheso lasan niroyin ti won n gbe kaakiri, ko si otito nibe rara.

Adeyemi so pe bo tile je pe oun ko si nibe, toun ko si le so pupo ninu e, sugbon gege bi nnkan toun gbo, iyen oro ti won fi to oun leti gege bi alaga ni pe ni nnkan bi aago mejo ale ojo Abameta Satide to lo lohun ni Awilo lo si adojuko Post Office nibi tawon ti won n fi bata oni taya sere (Skating ground) lati loo mu oti ti won n pe ni Skuchi.

O so pe nibi ti won ti n mu oti naa lo da bi eni pe awon SARS ti wa a wo o boya awon omo Yahoo wa nibe, ati pe bawon to n mu oti skuchi naa se rii pe awon SARS ti de lonikaluku won ti n sare ba ese won soro ki owo ma baa to won.

Alaga naa ni awon to gbe oro naa soun leti je ko di mi mo pe Awilo ti muti yo lojo naa, ko si fi be e riran daadaa, to fa a to fi loo kolu irin loju ona lale ojo naa, sugbon to tiraka lati dele.

O tesiwaju pe lojo Sande lo ranse pe okan lara awon ore e lori foonu pe ko wa a yoju soun lati se toju oun, sugbon nigba tiyen maa de be lorii pe aya e nibi to fi gba irin ti ga.

Itoju yi lo so pe won se titi ko too di pe won ranse sawon ebi e lati wa a woo, ojo Monde la gbo pe won gbe e lo si osibitu ijoba apapo, iyen FMC to wa ni Idi-Aba, Abeokuta, nibe lo si dake sii lojo naa.

Adeyemi so pe iyalenu lo je foun nigba toun gbo pe awon eeyan n gbe e kaakiri pe awon SARS wa a le awon eeyan lojo Monde, ti won si pa Awilo. O ni iro patapata gba a ni nitori pe awon SARS ko de agbegbe naa rara lojo ti won n so.

Gbogbo akitiyan AWIKONO lati dele awon Awilo, ka le gbo oro latenu awon ebi e paapaa awon to sunmo on lo ja si pabo nitori ti a ko ri eni juwe ile e fun wa titi ta a fi sakojopo iroyin yi tan.


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI