...Lesekese lo pariwo sita pe oun ko mo won ri
Ko tii seni to le
so ibi ti oro naa yoo ja si bayii lori bi awon gendekunrin ti won je omo egbe
okunkun merin kan ti won furasi pe won pa okunrin kan ti won n pe ni
Arsenal-Nice niluu Sagamu lai pe yii, to si je pe asiko ti won n ka boroboro ni
won so fawon olopaa SARS pe okan lara awon omo ile igbimo asofin nipinle Ogun
to gbajumo daadaa, iyen Onarebu Yinka Mafe to soju ekun Sagamu lo ran won ni
se.
Awon merin naa,
Olushola Adedeji; Olusegun Olalekan ti inagije n je Musket; Azeez ti won tun n
pe ni Anene ati Abolore ti won tun pe oun naa ni A.B la gbo pe won wa lara awon
ti Onarebu Mafe n san owo osu fun.
Ojo Tosde ose to
lo lohun la gbo pe asiri won tu leyin ti enikan ti won foruko bo lasiri loo
tawon olopaa lolobo pe oun mo awon to pa Arsenal-Nice, ati pe awon naa ni won n
da alaafia Sagamu laamu, ti won ko je kawon araalu sun oorun asundokan.
Esun yi lo mu
kawon olopaa ZIS to wa ni Obada-Oko niluu Abeokuta gbera lo siluu Sagamu lati
loo ko won, ti won si bere sii jewo fawon olopaa pe oloselu kan lo ran won.
Nigba to m fidi
isele naa mule, Dolapo Badmus to je alukoro olopaa Zone 2 niluu Eko so pe looto
lawon odaran naa ti jewo, ti won si tun je ko ye won pe Onarebu kan to gbajumo
daadaa lo ran won nise, sugbon ti iwadii si n lo lowo.
Lesekese tiroyin
naa ti te Mafe funra e lowo lo ti so pe iro lawon eeyan naa n pa, ati pe kawon
olopaa tete gbe ejo naa lo si kootu, koun si le tete wa a jeri gbe ara oun ni
kootu pelu boun tun se je agbejoro.
Siwaju sii ninu
iroyin min naa lose to koja yi la gbo pe Gomina Amosun ran Onarebu Yinka Mafe
pe ko lewaju awon janduku lati loo fiya je Onarebu Adebiyi Adeleye toun n soju
ekun Remo North latari pe o kuro ninu egbe oselu APC lo si egbe oselu PDP.
Onarebu Adebiyi la
gbo pe o bu enu ate lu bi Gomina Amosun ko se sise de ekun to n soju fun,
paapaa ilu Isara to ti wa, to je pe awon ibomin in lo n sise sii, paapaa ilu
Abeokuta, ti ko si boju wo iya tawon eeyan ekun naa n je.
Ojo Monde to koja
ni Onarebu Adeleye pe ipade awon oniroyin, nibi to ti so pe Onarebu Yinka Mafe
pelu iranlowo Gomina Amosun n dunkoko iku moun latari boun se fi egbe oselu APC
sile lo segbe oselu PDP, bee lo tun so pe won fesun kan oun pe oun sagbateru
awon omo egbe okunkun.
Eyi gan an la gbo
pe o bi Amosun ninu, ko da ti won tun loo fi SARS gbe nile e laaro kutu ojo
Tusde, to si je pe ojo keji ni won fi sile lahamo awon SARS to wa ni Magbon,
Abeokuta.
O ni oun ko soro
pe won yo oruko oun kuro ninu iwe eto ti won se lati fi gbe ade le Odemo tiluu
Isara Remo lori losu to koja, nibe naa ni woj tun ti ran awon toogi pe ko lu
oun, ti won si tun ja oun sihoho omoluabi.
Nigba to n b'AWIKONKO
soro lojo Wesde ose to koja ninu ofiisi e, alaga egbe oselu PDP nipinle,
Onarebu Sikirulai Ogundele bu enu ate lu iwa ti Amosun hu naa, to si so pe
onikaluku lo ni eto lati darapo mo egbe oselu to ba wuu, paapaa ti egbe oselu
tiru eni bee ba wa ti ko si te e lorun.
No comments:
Post a Comment