Se lawon ero to wa ni kootu koko-koko Ake Abeokuta la enu won
sile ti won ko le pa a de nigba ti won ri okan lara awon agba Tisa nile eko
fasiti Federal University of Agriculture Abeokuta, FUNAAB to n be adajo pe ko
ba oun tu igbeyawo olodun merinla to wa laarin oun ati oko oun ka.
Bo tile je pe kii se akoko re e ti iyaale ile naa, Arabinrin
Mojisola Olanike Adegunwa maa koko fara han nile ejo naa, ko too di pe adajo fa
iwe igbeyawo to so oun ati oko e, Alaaji Saola Adetona Adegunwa ya.
Ohun ta a gbo ni pe eemeji otooto ni ile ejo naa ti fiwe pe
Alaaji Saola Adegunwa pe ko yoju lati wa so tenu e, ati pe o le see se ko je pe
se niyawo e, Mojisola wa a paro mon on, sugbon ti Baale ile naa ko jale, ti ko
yoju.
Mojisola nigba to n fi bibeli bura lojo Tusde ose to koja yi pe
oun ko nii paro pelu gbogbo nnkan toun fe e so, so pe nnkan toun fe ni pe kawon
omo meji toun bi fun oko oun wa lodo oun lati maa toju won, o ni aaye wa fun
Alaaji Adegunwa lati wa maa yoju sawon omo naa nigba to ba wun.
Iyaale ile eni odun metadinlaadota (47) naa, to so pe igbeyawo
ibile (traditional wedding) lawon se je ko di mi mo pe ko se dandan ki oko oun
gbo bukata lori awon omo naa nitori pe agbara oun gbe e lati toju won, sugbon
to ba wun un lati da si bukata awon omo naa, ko si nnkan to buru nibe, nitori
pe oun ko le fi tipa muu.
Nigba to n gbe idajo kale, Oloye Akande O. O so pe pelu bi
Alaaji Adegunwa ko se yoju lemeeji otooto ti ofin la sile lati fiwe pe eni ti
won ba fesun kan pe ko yoju lati wa a so tenu e, o fi han daju pe Alaaji ko
nife si igbeyawo naa mo, to si je gege bi eri lati di mu fawon.
O tu igbeyawo naa ka pelu pelu ase pe awon mejeeji ko gbodo ba
ara won fa wahala, ti won gbodo gba alaafia laaye, bee lo pase pe awon mejeeji
lo letoo lati gbo bukata lori awon mejeeji naa, iyen Adetomiwa Adegunwa, omodun
mokanla ati Ademide Adegunwa toun je omodun mesan an.
No comments:
Post a Comment