Ileese kan to n ri si oro ipese ina lorileede
Naijiria, Transmission
Company of Nigeria (TCN) ti so pe awon ti setan lati fi kun agbara ina to wo
ipinle Ogun, ki ina si le maa wa daadaa bii ti tele.
Lojo Tosde ni oga agba ileese naa,
Ogbeni Gur Mohammed so eyi niluu Ijebu-Ode nibi ti won ti loo fi ero amunawa
(transformer) ti agbara ko din ni 60MA, 132/133KV lole.
O ni awon yoo ko awon ileese agbara ina
merin otooto (four substations of 330KVA capacity) kaakiri ipinle Ogun, ti yoo
si le je ki eto oro aje orileede yi tubo le gbe peeli sii.
Awon agbegbe naa ta a gbo pe won fe e
ko won si ni Ogijo (Sagamu), Agbara, Mountain of Fire Ministry lopopona marose
Eko si Ibadan ati Arigbajo (Ifo), bo tile je pe ise ti bere lawon agbegbe naa,
sibe o so pe ise ti fe e pari.
Nigba
to n soro, olori awon osise gomina, Oloye Tolu Odebiyi to soju gomina Ibikunle
Amosun dupe lowo ileese
naa fun atileyin won, paapaa pelu bi won ko se dawo duro.
Lara awon to
wa nibi eto naa ni Onarebu Olusegun Gbeleyi to je oludamonran gomina lori oro
ina atawon min in.
No comments:
Post a Comment