Owo te omo iya meji to n digun jale - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, June 25, 2018

Owo te omo iya meji to n digun jale

Bi ki ba a se pe awon olopaa SARS tete yoju ni, bo ya awon gendekunrin merin, eyi tawon omo iya meji wa lara won towo awon araalu te lose to lo lohun ko ba ti deni igbagbe bayii, nitori pe die lo ku ki won dana sun won niluu Ipokia.

Gege ba a se gbo, Sunday Avoseh, eni odun matundinlogoji (35); aburo e, Taye Avoseh, omodun marundinlogbon (25); Abiodun Kodewu, eni odun metadinlogoji (37) ati Salau Ogendengbe toun je omodun mejilelogbon (32) la gbo pe won ko nise meji ju ki won maa ji ewure ati okada gbe lo, ti won a si tun ta si Cotonou.

Bo tile je pe won ni olori won, Segun Avoseh ti na papa bora, ti won si n wa titi dasiko ta a sakojopo iroyin yi tan, sibe oun ta a gbo ni pe oun gan an lo maa n fi moto e gbe awon toku ko sibi ti n ji eran gbe, ti won tun n fagidi gba okada lowo awon to nii.

Nigba towo maa te won lopin ose to lo lohun, Abiodun ati Taye la gbo pe won lo lati gba okada lowo Baale ile kan ta a ko tii moruko e dasiko yi, sugbon tiyen yari mo won lowo.

AWIKONKO gbo pe nibi ti won ti n fa oro naa ni Sunday, Salau ati Segun ti yoju lati lu okunrin olokada naa lalubami. Ko pe la gbo pe awon araalu ti won ti n wa won ti pe de be lati da si.

Bi won se rii pe asiri awon ti tu pe awon fe e lu okunrin olokada naa ni jibiti ni won ti n gbiyanju lati na papa bora, sugbon ti won ko je ko lo yato si Segun to raaye salo.

Ibe la gbo pe won ti gbe won lo sodo Baale agbegbe naa lati loo ro ejo enu won. Ohun ti won si so ni pe awon ti n se e tipe, kii se akoko re e.

Taye nigba to n soro so pe igba kan wa tawon ji eran mewaa gbe leekan soso, to je pe moto Segun lawon fi ko awon eran naa, tawon si loo ta a si orileede olominira Benin. O tun so pe lopo igba lawon maa n gbe awon okada naa gba ori omi soda si orileede Benin ta won n ta a sii.

Sunday ni ti e so pe "Okada meta pere ni mo si ri gba laye mi. Ti mo ba ti rii pe won paaki okada sibi kan, ibe ni maa ti yo kele loo ji gbe salo lai je pe enikeni mo si. Mi o le ka iye ewure ti mo ti ji gbe, to je pe igba kan wa towo olopaa ti te mi to je pe awon obi mi ni won wa a beeli mi jade. Ti ko ba si owo lowo mi, mo maa n ta awon eran naa ni, bee ni mo tun maa n pa a lati je pelu awon ebi mi."

Bawon odo ilu se fe maa lu won, ti won si n so pe.kawon pa won lesekese la gbo pe Baale naa ti ranse sawon SARS lati wa a ko won lo lati foju won bale ejo nitori pe won ti lawon eeyan repete lekun jaye.

AWIKONKO gbo pe okada mewaa ni won ti gba lowo won, ta a si gbo pe won si ni Magbon nibi ti won ti gbategun lowo bayii.

Alukoro olopaa ipinle Ogun, Abimbola Oyeyemi jeri soro naa, o si so pe iwadii si n lo lowo.


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI